Àwọn tí a ti mọ̀ sí ọba tẹ́lẹ̀, kí ó tó dií pé òyìnbó amúnisìn gba ipò kúrò lọ́wọ́ ọba, tí Nàìjíríà kúkú wa fagi le pátápátá ní ọdún ẹgbàá ó dín mẹ́ta-dín-lógójì tí wọ́n sọra wọn di “republic,” tí kò dẹ̀ tún wá sí àyè fún ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ti wá bá Ogúnwùsì Adéyẹyè tí ó pe ara rẹ̀ ní Ọọ̀ni Ifẹ̀ o, pé kí ó jọ̀wọ́ jàre fa àwọn mọ́ra (èyíinì, àwọn tí ó wá ọ̀ún, tí wọ́n sì jẹ́ láti ìpínlẹ̀ Ìṣèjọba Ọ̀yọ́, èyí tí agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà pè ní Kwara àti apá kan Kogi); wọ́n ní kí ó fàwọ́n mọra, kí ìyókù ilẹ̀ Yorùbá máṣe rí àwọn gẹ́gẹ́bí Yorùbá tí kò tó Yorùbá ẹgbẹ́ wọn.
Wọ́n ní àwọn kò fẹ́ pàdánù ìjẹ́-Yorùbá wọn, àti iyì wọn. Wọ́n ní àwọn fẹ́ ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú orísun wọn, yàtọ̀ sí ibi tí àwọn òpùrọ́ Nàìjíríà npè ní “north central” tí wọ́n ti so wọ́n mọ́.
Lára àwọn tí wọ́n ṣì ka ara wọn sí ọba yí ni ọba Kabba, Mopa, Ejuku, àti Isin.
Wọ́n ní ibi tí Nàìjíríà ka àwọn mọ́ ti sú àwọn. Wọ́n ní àwọn ò ní ìdàgbàsókè níbẹ̀. Wọ́n ní àwọn fẹ́ padà sílé.
Ohun tí ó ṣeni láanú ní ọ̀rọ̀ yí ni pé, gbogbo ohun tí wọ́n nsọ wọ̀nyí ni lára ìdí tí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ṣe jáde kúrò lára Nàìjíríà ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjì-lé-lógún, tí a dẹ̀ ti gbé ìjọba wa wọlé láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ọdún tí a wà yí, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún; nítorí náà, Adéyẹyè Ògúnwùsì kọ́ ni ẹni tí ó yẹ kí wọ́n lọ sukún bá!; nṣe ni ó yẹ kí wọ́n mọ̀ pé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) ni ìdáhùn sí gbogbo ìṣòro wọn tí wọ́n kà sílẹ̀ wọ̀nyí; àbi ṣé wọ́n á ní àwọn ò gbọ́ nípa D.R.Y ni? Àmọ́, a ò sọ pé ọba máa wà o!
Ìyẹn kọ́ la nsọ! Ohun tí a nsọ ni pé a ti padà sí ORÍSUN wa; bẹ́ẹ̀ ní kò sí ìyàtọ̀ láarin Yorùbá mọ́! Ẹ jọ̀wọ́, ẹ bá wa sọ fún wọn! Agbègbè tiwọn yẹn ni a npè ní Ìpínlẹ̀ Ìṣèjọba Ọ̀yọ̀, ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y)
Kò mà dára kí ènìyàn wà ní àìmọ̀kan o! Ohun tí ó ti tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ ní wọ́n ṣì npòngbẹ rẹ̀! Wọn ò tún wá rẹ́ni lọ bá, wọ́n lọ bá èyí tó pera ẹ̀ ní Ọ̀jájá!
Ẹ jọ̀wọ́, gbogbo ọmọ Ìpínlẹ̀ Ìṣejọba Ọ̀yọ́ (èyí tí Nigeria npè ní Kwara pẹ̀lú apákan Kogí), aò sí nínú Nàìjíríà mọ́ o! Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ni a wà o!
Ẹ bá wa sọ fún gbogbo àwa ọmọ Yorùbá tí a npòngbẹ orísun wa, bẹ́ẹ̀ o. Ìrọ̀rùn ti dé.
Kí a máa retí ijọ́ tí ìjọba wa, pẹ̀lú àtìlẹ́hìn Olódùmarè fún Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, máa fi àmì síta pé ọjọ́ àjọyọ̀ wa ti dé! – nígbà tí a máa jáde láti ṣe àjọyọ̀ nlá náà. Ṣùgbọ́n a ò sọ pé ọba kankan máa wà o!