Ní àti ayébáyé ni àwọn babanlá wa ní ilẹ̀ Yorùbá ti mọ̀ nípa ìlò ewé, egbò, èso, irúgbìn èso, àti oríṣiríṣi ohun ní àyíká wa láti ṣe ètò ìwòsàn ara fún ọmọ Yorùbá.
Olódùmarè, nípa ọgbọ́n inú àti ìtọnà, àti ìwádi àwọn baba wa, ni ó fi nkan wọ̀n yí hàn wọ́n. Èyí túmọ̀ sí pé Yorùbá ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti wa, tí ó dẹ̀ njẹ́ fún wa, kí òyìnbó ó tó gòkè odò wá bá wa.
Wọ́n fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ àti oríṣiríṣi àrékérekè gba gbogbo nkan wọ̀nyí lọ́wọ́ wa, wọ́n sì wá sọọ́ di ohun ìríra, tí àwọn tàgbà tọmọdé wa, lóde òní, máa ntàbùkù bá, látàrí pé a ti kàwé, a ti “lajú,” a ti wá gbà pé èyí tí òyìnbó bá ti gbé jáde, ìyẹn nìkan ni Ọlọ́run fọwọ́ sí! Háà! Àwọn òyìnbó wọ̀nyí ṣe iṣẹ́ ibi fún wa gan-an ni o!
Ìròhìn kan tí a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára ní ó tún gbé ọ̀rọ̀ yí jáde lóni, nítorí ìròhìn náà sọ nípa èso igi kan, nígbà náà lọ́hun, tí àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ kan rí ní agbègbè Queensland ní ìlú Australia, tí wọ́n sì ríi pé, nígbàtí wọ́n dán-an wò lára àwọn ẹranko kan, oje tí wọ́n rí fà láti ara irúgbìn èso-igi náà ṣíṣẹ́ dáradára nípá mímú àrùn jẹjẹrẹ, kí ó kúrò lára àwọn ẹranko náà, ní bíi ọ̀sẹ̀ kan-àbọ̀ tí wọ́n ti fa oje yí sí ara àwọn ẹranko ọ̀ún, tí wọ́n sì wá nwòye pé àwọn á bẹ̀rẹ̀ síí má gbìyànjú láti wo bí ọmọ ènìyàn ṣe le lo oje yí náà fún ìwòsàn jẹjẹrẹ.
Ibi tí wọ́n bá ọ̀rọ̀ náà dé níjọ́ náà lọ́hun ní orílẹ̀-èdè wọn kọ́ ni ó ṣe pàtàkì fún wa.
Èyí tí ó ṣe pàtàkì fún wa ni pé, àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, D.R.Y, ní láti padà sí ẹsẹ̀ àárọ̀ wa, nípa ìwòsan!
A máa bẹ Ẹlẹ́da wa, kí ó jọ̀wọ́, bojú àánú wò wá, kí á le rí òtítọ́ àti òdodo ti ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ tí Ó ti jogún fún ìran Yorùbá, nípa ìwòsàn, kí á yé rò pé èyí tí òyìnbó bá ti gbé lé wa lọ́wọ́ yẹn nìkan náà ni òpin ètò ìwòsàn!
Ṣé òyìnbó tí kò nífẹ wa tẹ́lẹ̀, ni a máa máa gbára lé lọ ni? Òyìnbó ò nífẹ ara ẹ̀ lápa kan pàápàá, ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé ájẹ́ wọn tí ó ti níkà méjì máa nfi ìkan ṣera ẹ̀, nígbà míì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aláwọ̀dúdú ni wọ́n máa nlépa láti parun.
Ní kété tí Olódùmarè bá ti bá wa ṣe àṣepé ojúkorojú lílé àwọn agbésùnmọ̀mí ajẹgàba kúrò lórí ilẹ̀ wa, ìjọba D.R.Y, dájú-dájú máa ṣe ètò bí ohun gbogbo á ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní bárajọ nípá ṣíṣe ìwádi àwọn ohun ìjìnlẹ̀ tí ó jọ mọ́ ètò-ìwòsan fún ọmọ Yorùbá.
A mọ̀ pé ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n náà, tí ó bá dára, ni a máa fi kún ọgbọ́n tiwa, ṣùgbọ́n láì pe ọgbọ́n tiwa bí ó ṣe jẹ́ – èyíinì, ká pèé ní pàtàkì, àti ìpìlẹ̀, ohun tí a bá nṣe, ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n kankan, bí ó ti wù kó dára tó, kò léè gba Ìran wa là.
Àlááfíà ni fún Ìran Yorùbá; Olódùmarè yíò sì ràn wá lọ́wọ́, títí tí nkan ìbílẹ̀ wa nípa ìwòsàn yíò fi jẹ́ gbòngbò, ìpìlẹ̀, àti àṣepé ètò ìwòsàn wa.