Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yí, ó kọjá à fẹnu sọ. Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, tí máa ń fi yé wa láti àtẹ̀yìnwá pé, orílẹ̀-èdè ni àwa Ìran Yorùbá àti pé Èdè ni a fi ń júwe orílẹ̀-èdè; bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ti máa ń fi yé wa pé, ibi tí wọ́n ń pè ní Nàìjíríà kìí ṣe orílẹ̀-èdè!
Ṣùgbọ́n ohun kan tí Màmá wa ò gbé síta títí di àìpẹ́ yí tí ó tó àsìkò fún wọn láti gbe síta, ni pé kíni Nàìjíríà jẹ́ gan-an? Ìbá ṣe pé àwọn tó ń jẹgàba lórí ilẹ̀ wa kò ṣe bẹ́ẹ̀ ni, bóyá ohun tó wù kí Nàìjíríà jẹ́ kò bá má tilẹ̀ kàn wá rárá.
Ṣùgbọ́n àìbìkítà wọn ni ó jẹ́ kí MOA sọ pé àsìkò ti wá tó báyi, láti tú àṣírí agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà àti àwọn Gẹ̀ẹ́sì tí ó ṣe àtọwọ́dá aríremáṣe Nàìjíríà, láti wá tú àṣirí ọjọ́ pípẹ́ yí fún gbogbo Ayé gbọ́.
Èyí ló mú kí MOA, wá ṣí aṣọ lójú eégún àwọn Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tí wọ́n sì fi tó gbogbo àgbáyé léti pé, Nàìjíríà kìí ṣe Orílẹ̀-Èdè, bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe Ilẹ̀-Àjogúnbá Ìran kankan, èyí tó túmọ̀ sí pé, ibi tí wọ́n ń pè ní Nàìjíríà kò sí ẹ̀yà Ìran tó lè fọwọ́ sọ’yà pé ilẹ̀-àjogúnbá àwọn ni! Kò sí ńkan tó ń jọ bẹ́ẹ̀, kò sì sí ìran kankan bẹ́ẹ̀!
Èyí ni àṣírí tí MOA tú sí àgbáyé ní àìpẹ́ yí, wọ́n sì tú àṣírí yí fún àwọn ìlú àti orílẹ̀-èdè káàkiri àgbáyé pé Nàìjíríà kìí ṣe orílẹ̀-èdè bí kò ṣe àtọwọ́dá àwọn Gẹ̀ẹ́sì. Nàìjíríà jẹ́ àpapọ̀ ilẹ̀ tí Gẹ̀ẹ́sì fi ipá kó papọ̀ sí abẹ́-òrùlé ìṣàkóso kan ṣoṣo, tí wọ́n wa pa irọ́ fún Gbogbo àgbáyé pé orílẹ̀-èdè ni wọ́n!
Irọ́ nlá yí ni Ilú Gẹ̀ẹ́sì ti tà fún gbogbo àgbáyé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, tí àgbáyé sì ti ra irọ́ yí! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn ọ̀gá láàárín àwọn àmúnisìn-ara-wọn mọ̀ nípa irọ́ yí, àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ tó kù wọn ò mọ̀! Wọn ò mọ̀ pé Gẹ̀ẹ́sì pa irọ́ fún àgbáyé, pé orílẹ̀-èdè ni Nàìjíríà.
Ipá àti ẹ̀tàn ni Gẹ̀ẹ́sì fi ṣe àtọwọ́dá àti ìkójọpọ̀ Nàìjíríà fún ànfààní ọrọ̀-ajé Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n sì wá ń fi òfegè àtọwọ́da tí wọ́n ńpè ní nàìjíríà ọ̀hún jẹgàba lórí àwọn oríṣiríṣi ìran.
Àṣírí tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì fi pamọ́ fún gbogbo àgbàyé ni MOA tú síta, àwọn amúnisìn wọ̀nyí ò rò tẹ́lẹ̀ pé àṣírí náà máa tú! Títú tí Màmá wa MOA tú àṣírí náà síta, wá dàbí ìgbà tí a fa ẹní kan kúrò lábẹ́ ẹsẹ̀ ẹni ó dúró lée lórí, tó nsọ pé báyi ni òun ṣe tó! Àfi ìgbà tí Màmá wá fa ìran Yorùbá yọ kúrò lábẹ́ ẹsẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ni Àṣírí bá tú!
Ẹ̀sín Gẹ̀ẹ́sì ti wá wà ní ìgboro-ayé báyi, nítorí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìlú àti Orílẹ̀-Èdè káàkiri àgbáyé ni Màmá wa kọ ìwé yí sí, tí wọ́n sì tú àṣírí àti Irọ́ tí Gẹ̀ẹ́sì ti ń pa fún àìmọye ọdún síta.
Màmá kò dúró níbẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n wọ́n tún rọ̀ gbogbo àwọn olórí-ìlú àti olórí àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri àgbáyé pé kí wọ́n kàn sí ìṣàkóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, kí wọ́n sì sọ fún Gẹ̀ẹ́sì pé, ní kíákíá kí Gẹ̀ẹ́sì máṣe jẹ́ kí ogun tí Nàìjíríà npète-pèrò rẹ̀ ó wá’yé, àti pé kí ìjẹgàba Nàìjíríà lórí ILẸ̀-AṢÈTÒ-ARA-ẸNI ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) kí ó d’opin bayi!