Ní gbogbo ìgbà ni àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa fún oore ńlá tó ṣe fún wa, fún òmìnira àìlópin èyí tó ti ọwọ́ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe fún àwa ọmọ Aládé.

Bẹ̀rẹ̀ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún tí a kéde òmìnira orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ni ìran Yorùbá ti kúrò nínú àjàgà àwọn amúnisìn.

Kò sí ohun tí a leè fi òmìnira wé, nítorí ìdàkejì òmìnira náà ni ìgbèkùn. Bí ẹ̀dá bá sì wà nínú ìgbèkùn kò sì ohun tó lè dá ṣe fúnra rẹ̀. Kò ní leè dá’nú rò, kò ní leè ṣe bó ti fẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní sí ìdàgbàsókè kankan fún irú ẹni bẹ́ẹ̀.

Irú ipò yí ni ìran Yorùbá wà fún àìmọye ọdún kí Olódùmarè tó tú wa sílẹ̀ nípasẹ̀ màmá wa MOA, gbogbo ìgbà ni wọ́n sì máa ń sọ fún wa wípé, títí láé ni oore tí Olódùmarè ṣe yí, nítorí pé àlàkalẹ̀ ètò ìmójútó ará ìlú tí Olódùmarè gbé fún wọn, ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ fi kún-un tàbí yọ kúrò níbẹ̀. Bí yóò ṣe wà nìyí títí òpin ayé.

Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P), ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa nígbà gbogbo, gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe sọ láìpẹ́ yí wípé lójoojúmọ́ ni kí a máa fi ọkàn ìmoore wa hàn sí Ọlọ́run fún oore ńlá tó ṣe fún wa.

Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ti di orílẹ̀ èdè Olómìnira títí láé, kò sí ẹnikẹ́ni tó leè yí padà.