Ìgbéyàwó jẹ́ ohun pàtàkì nínú àṣà àti ìṣe ilẹ̀ Yorùbá, ó sì jẹ́ ohun tí kò ṣeé fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn ni ìgbésí ayé ènìyàn. Ní ilẹ̀ Yorùbá, tí ọmọkùnrin bá ti bàlágà ni àwọn òbí rẹ̀ yóò ti máa sọ fún un wípé àkókò ti tó fún láti ní aya, ṣùgbọ́n àwọn ìgbésẹ̀ kan wà tí wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀lé lẹ́sẹẹsẹ. Àwọn ìgbésẹ̀ náà ni ìwọ̀nyí:
Ìfojúsóde, Alárinà, Ìshíhùn/Ìjọ́hẹ̀n, Ìtọrọ, Ìdána, Ìpalẹ̀mọ́, Ọjọ́ ìgbéyàwó, Ẹsẹ̀ ìyàwó wíwẹ̀, Ìbálé.
Ẹ jẹ́ kí a ṣe àlàyé ní ṣókí lórí àwọn ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan :
1. Ìfojúsóde: Àkókò yí ni ọmọkùnrin máa ń fi ojú sílẹ̀ láti wá ọmọbìnrin tí ó wù ú láti fẹ́.
2. Alárinà : Tí ọmọkùnrin bá ti rí ọmọbìnrin tí ó wù ú láti fẹ́, alárinà ní yóò wà láàárín àwọn méjèèjì tí yóò máa ṣe ìwádìí irú ilé tí ọmọbìnrin náà ti jáde wá, tí alárinà bá sì ti ríi dájú pé láti ilé ire ni ọmọbìnrin náà ti wá, iṣẹ́ yóò wá bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu, alárinà ni yóò parí iṣẹ́ tó kù láàárín àwọn méjèèjì.
3. Ìshíhùn/Ìjọ̀hẹ̀n: Ipele yí ní àkókò tí àwọn ẹbí obìnrin gbà láti fẹ́ ọmọkùnrin, ẹbí ọmọkùnrin náà yóò wá lọ sí ilé àwọn ọmọbìnrin náà láti lọ tọrọ ìyàwó, àwọn ẹbí ọmọbìnrin yìí yóò wà fún àwọn ẹbí ọmọkùnrin náà ní ọjọ́ díẹ̀ láti padà wá fún èsì, ṣùgbọ́n kí ó tó di àkókò tí wọn dá ọ̀hún, àwọn ẹbí ọmọbìnrin yóò ti lọ ṣe ìwádìí nípa ìdílé àwọn ọmọkùnrin náà, bí ifá kò bá f’ọre, ibi tí ọ̀rọ̀ náà yóò parí sí nìyẹn, ṣùgbọ́n bí ifá bá f’ọre wọ́n yóò ránsẹ́ sí àwọn ẹbí ọmọkùnrin náà fún èsì.
4. Ìtọrọ: Lẹ́yìn tí àwọn ẹbí ọmọbìnrin ti gbà láti fún àwọn ẹbí ọmọkùnrin náà aya, ìtọrọ ni ó kàn, àwọn ẹbí ọmọkùnrin yóò wá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí ọmọbìnrin náà láti wá tọrọ rẹ̀.
5. Ìdáná: ìgbésẹ̀ yí ni ó kàn lẹ́yìn ìtọrọ. Àwọn ẹbí ọmọkùnrin yóò kó oríṣiríṣi ẹrú ìdána lọ sí ilé ọmọbìnrin naa, lára àwọn èròjà ìdána náà nì wọ̀nyí: orógbó, obì, oyin, ìrèké, iyọ̀, ẹja àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n yóò sì máa fi wúré fún ọkọ àti aya ní ọ̀kanòj’ọ̀kan.
6. Ìpalẹ̀mọ́: Àwọn ẹbí méjèèjì ni yóò máa múra fún ayẹyẹ ìgbéyàwó, ìyàwó pàápàá yóò ti máa gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ àwọn ìyàwó ilé.
7. Ọjọ́ ìgbéyàwó: Ní ọjọ́ ìgbéyàwó, jíjẹ, mímu yóò ti wà lorísìírísìí ní ìdílé méjèèjì, ìyàwó àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yóò máa lọ láti ojúlé dé ojúlé láti dágbére fún àwọn ẹbí rẹ̀ tí yóò sì máa sún ẹkún ìyàwó. Alẹ́ ni ìyàwó máa ń lọ sí ilé ọkọ rẹ̀ ní ayé àtijọ́.
8. Ẹsẹ̀ ìyàwó wíwẹ̀: Kí ìyàwó tó wọlé ọkọ rẹ̀ ni wọn yóò fi omi fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì tún tẹ igbá fọ́. Ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá ni pé, ẹsẹ̀ tí wọ́n fọ̀ yí láti fọ̀ ibi dànù ni àti pé, iye tí igbá náà bá fọ́ sí ní iye ọmọ tí ìyàwó yóò bí.
9. Ìbálé: Ìbálé túmọ̀ sí pé ìyàwó náà kò tíì mọ ọkùnrin. Ìyàwó tí wọ́n bá bá nílé, iyì gidi ni fún ẹbí rẹ̀. Láti ilé ọkọ, wọn yóò fi ẹ̀kún ìsáná ránsẹ́ sí àwọn ẹbí ìyàwó pẹ̀lú aṣọ funfun. Ìtìjú ńlá sì ni fún ẹbí ìyàwó tí wọn kò bá bá nílé.
Nítorí náà, àwa ọmọ Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó rán ìránṣẹ́ rẹ̀ sí wa ní àkókò yí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ṣé ẹ rántí wípé, màmá wa ti sọ fún wa wípé, gbogbo àwọn àṣà wa wọ̀nyí ni a ó padà sí gẹ́gẹ́ bí àwọn babańlá wa ti ń ṣe láti ìgbà ìwáṣẹ̀. A kú oríire ò, gbogbo àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá.