Ní orí ẹ̀rọ ayélujára ni a ti rí ìròhìn ọkùnrin kan tí ó pera rẹ̀ ní Táíwò Agbájé, ẹni tí ó fi àdá ṣá tẹ̀gbọ́n-tàbúrò méjì, ọmọ ọdún mẹ́san àti ọmọ ọdún méje, tí àwọn ọmọ méjèèjì ọ̀ún sì jẹ́ ọmọ-bíbí àbúrò Táíwò náà fúnra rẹ̀. Èrèdí kí ló ṣe pa wọ́n o?
Ó ní èṣù ni! Àà, ẹ mà jọ̀ọ́, èwo ni ti èṣù nínú ẹ̀ o? Ṣebí ògbóntagì nínú àwọn tí ó ti lọ ni èṣù; bóyá kẹ̀ ó fẹ́ sọ pé àṣìtáánì. Ìyẹn bẹ́ẹ̀.
Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣe pàtàkì sí wa ni pé, Yorùbá ni ọkùnrin yí nsọ lẹ́nu, tí orúkọ rẹ̀ tún jẹ́ orúkọ Yorùbá, bẹ́ẹ̀ náà ni, agbègbè Abẹ́òkúta ní ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba, ní ìpínlẹ̀ Ògùn wa, níbi ti agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà fi Dàpọ̀ Abíọ́dún sí tó njẹgàba lórí ilẹ̀ wa, ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀!
Ṣé ọkùnrin Táíwò yí npurọ́ ni pé kò sí nkan tí bàbá àwọn ọmọ náà, tí ó jẹ́ àbúrò òun fúnra rẹ̀, pé kò sí nkan tó ṣe fún òun, tàbí ó ṣì ní nkan-kan tí ó jẹ́ àṣírí ọ̀rọ̀ náà, èyí tí Táíwò kòì tíì jẹ́wọ́ rẹ̀?
Èyí ó wù kó jẹ́, tiwa ni pé, tí alákọrí Nàìjíríà bá ti kúrò lórí ilẹ̀ wa láti ìgbà tí a ti di orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni, ní ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún tí a wà nínú rẹ̀ yí, kí ìjọba wa tí a ti búra wọlé fún ní ìgbà náa ti wọlé sí oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa káàkiri Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, láti máa ṣe iṣẹ́ láì sí ìdènà kankan, njẹ́ eléyi ìbá ti ṣẹlẹ̀ bí? Dájú-dájú, àti Dàpọ̀ Abíọ́dún àti àwọn ọ̀gá rẹ̀ ní Nàìjíríà kò ní lọ láì jìyà!
Ó mà ṣe o!
Ọ̀ràn dídá ìjọba abésùnmọ̀mí Nàìjíríà túbọ̀ npọ̀ síi, lójoojúmọ́!
Gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ẹ má ṣe gbàgbé irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ abanilọ́kànjẹ́ báwọ̀nyí, kí ẹnikẹ́ni máṣe pète fí fi ọwọ́ pa àwọn ọ̀daràn agbésùmọ̀mí nàìjíríà bí ẹni tí kò lí ọ̀rọ̀ apànìyàn lọ́rùn! Ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ni ó jẹ̀bi eléyi o! Háà! Èèmọ̀!