Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, D.R.Y.
Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀ èdè tí Olódùmarè kẹ́ pẹ̀lú àlùmọ́ọ́nì lorísìírísìí ní àgbáyé, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) jẹ́ ọ̀kan gbòógì. Bí a ṣe ní àlùmọ́ọ́nì ti ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn omi lorísìírísìí tó leè máa mú owó wọlé sí orílẹ̀ èdè wa.
Ilẹ̀ ọlọ́ràá tí Olódùmarè fi kẹ́wa ńkọ́? Kò sí ohun tí a gbìn sínú rẹ̀ tí kò ní mú èso jáde. Iṣẹ́ ọ̀gbìn nìkan tó fún orílẹ̀ èdè D.R.Y láti sọ wá di ọlọ́rọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe sọ láìpẹ́ yí wípé, Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) yóò máa wín ni, aò ní tọrọ.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé ni yóò máa wá wo àwòkọ́ọ̀ṣe wa. Gbogbo àwọn ibùdó àwòyanu tí Olódùmarè dá sí ilẹ̀ Yorùbá tí kò sí irú rẹ̀ ní ibikíbi lórí ilẹ̀ ayé yìí, gbogbo wọn ni ìṣàkóso D.R.Y yóò mójú tó tí yóò sì di orísun ìbùkún àgbọ́n-ọ̀n-gbẹ fún orílẹ̀ èdè wa.
Gẹ́gẹ́ bí ìran Yorùbá tún ṣe jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé, a óò lo ọpọlọ tí Olódùmarè fún wa, àwọn àlùmọ́ọ́nì àti ohun rere gbogbo tí a ní láti ríi dájú pé orílẹ̀ èdè D.R.Y kò tún tòṣì mọ́.