Àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ màmá wa, ìyá ìran Yorùbá, Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe fún ìran Yorùbá, Olódùmarè lo màmá wa láti kó wa jáde kúrò nínú oko ẹrú pẹ̀lú ìrọ̀rùn láìsí ìtàjẹ̀sílẹ̀ tàbí ogun.

Èyí ló mú kí màmá wa MOA sọ nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, I.Y.P sọ láìpẹ́ yí wípé, ìgbà mẹ́rin láàárín ọdún ni a óò máa ṣe àjọyọ̀ òmìnira wa kúrò nínú àkójọpọ̀ àti ìgbèkùn Nàìjíríà. 

Oore Olódùmarè lórí ìran Yorùbá pọ̀, kò ṣeé ròyìn tán, gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ wípé, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé oore tí Olódùmarè ṣe fún àwa ìran Yorùbá, nígbà gbogbo ni kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run kí a sì máa sìn ín. 

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ wípé, Olódùmarè kẹ́ ìran Yorùbá púpọ̀ pàápàá pẹ̀lú èdè wa, kò sí ẹ̀yà náà ní àgbáyé tó mọ oríkì Olódùmarè bí ìran Yorùbá. Ṣé tí onírúurú ohun èlò orin ni ká sọ ni, tàbí kí a sọ ọ̀rọ̀ di orin, tàbí ní kíki Olódùmarè ìran Yorùbá ni àkọ́kọ́. 

Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa gbáradì fún àjọyọ̀ tó ń bọ̀ lọ́nà yí, ìran Yorùbá ti ṣe oríire, ìgbádùn ló kù fún t’èwe t’àgbà ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y). Ní kété tí àwọn adelé wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso wa ní ìpínlẹ̀ méjèèje ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, nígbà náà ni a óò bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè fún ìran Yorùbá nípasẹ̀ màmá wa MOA

Kòsí àní-àní, ilẹ̀ Yorùbá ti dúró gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀ èdè aṣàkóso-ara-ẹni, gbogbo àgbáyé ló sì ti mọ̀ èyí.

Democratic Republic of the Yoruba

Àgbàrá ò ní òhun òní’lé wó, onílé ni kò ní gbà fun