Láti ìgbà ìwásẹ̀ ni àwọn babańlá wa ti ń lo ọgbọ́n àtinúdá wọn láti mú ayé rọrùn fún ara wọn. Ọgbọ́n nípa aṣọ wíwọ̀, oge ṣíṣe, iṣẹ́ ọnà, ìkòkò mímọ, ilà kíkọ, ìlù lílù, ère gbígbẹ́, apẹ̀rẹ̀ hínhun, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. A ma ṣe àwárí ara wa ní kété tí àwọn Alákóso wa bá ti bọ́sí oríkò ilé íṣẹ Aṣojú orílẹ̀ èdè D.R.Y.
NÍ ayé àtijọ́, oge ṣíṣe jẹ́ ńkan tí àwọn babańlá wa tí wọn kò fi ọwọ yẹpẹrẹ mú, tí wọ́n bá ńlọ sí òde àríyá àwọn bàbá wa á múra ní ìmúra ọmọlúàbí, wọ́n á fi ìlẹ̀kẹ̀ sí ọrùn àti ọwọ́.
Bákan náà àwọn ìyá wa á ṣe oge wọn ní ti ọmọlúàbí, wọ́n á ṣe irun tó rẹwà. Ìmúra àwọn bàbá àti ìyá wa yìí mú ìwúrí àti iyì bá Ìran Yorùbá.
Gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe ma ń sọ fún wa pé, àwọn àṣà, iṣe àti ọgbọ́n àtinúdá àwọn babańlá wa jẹ́ ohun tí a má fi sí ìṣe tí yóò jẹ́ kí ògo orílẹ̀ èdè wa búyọ.
Oríṣiríṣi ọgbọ́n àtinúdá ni Olódùmarè fi fún wa fún àǹfààní àti ìgbé-lárugẹ orílẹ̀ èdè wa D.R.Y. Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ẹ jẹ́ kí a lo ọgbọ́n àtinúdá tí Olódùmarè fi fún wa àti èyí tí a jogún bá fún ilẹ̀ wa Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).
ÌKÌLỌ̀ FÚN GBOGBO Ẹ̀YIN ÀGBẸ̀
Ẹ má ṣe gba irúgbìn GMO lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ọ̀nà míràn láti pa àwa aláwọ̀ dúdú run ni, àìsàn oríṣiríṣi ni irúgbìn yí yóò fà sí àgọ́ ara ẹnití ó bá jẹẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni náà kò ní leè bí ọmọ mọ́, àti wípé, ilẹ̀ tí wọ́n bá gbin irúgbìn yí sí yóò di aṣálẹ̀ tí kò sì ní leè mú èso jáde mọ́.Fún ìdí èyí, ẹni tí ọwọ́ ìṣàkóso Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá bá tẹ̀, ẹ̀sùn ìpànìyàn ni ò. Nítorí náà, a rọ gbogbo ẹ̀yin Indigenous Yoruba People (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) wípé, ibikíbi tí ẹ bá ti rí ẹni tí ó bá gba irúgbìn yí tàbí ẹni tí ó fún wọn, ẹ bá wa ya àwòrán wọn, àti ẹni tí ó fún wọn, àti ẹni tí ó gbáà, apànìyàn ni àwọn méjèèjì.
Ẹ tọ́jú àwọn irúgbìn àbáláyé tó wà lọ́wọ́ yín.