Màmá wa, Ìránṣẹ́-Olódùmarè sí Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, tún ti rán àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) létí, ní àìpẹ́ yí, pé, gẹ́gẹ́bí àwọn ṣe sọ fún wa ní ìgbà kan rí, wọ́n ní kété tí àwọn Alákoso-Adelé wa, bá ti wọ inú oríkò-ilé-iṣẹ́-ìṣàkóso wa káàkiri Orílẹ̀-Èdè wa, ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣe, ni pé wọ́n á ṣí gbogbo ọgbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n á tú gbogbo ẹni tí ó wà ní ọgbà-ẹ̀wọ̀n àti àtìmọ́-‘lé sílẹ̀.
Ètò ti wà fún eléyi. Ìdí ni pé kìí ṣe lábẹ́ òfin D.R.Y ni wọ́n fi gbé wọn sí ẹ̀wọ̀n tàbí tì wọ́n mọ́’lé, ìdí tí wọ́n fi jù wọ́n sínú ẹ̀wọ̀n tàbí tì wọ́n mọ́’lé kò kàn wá! Bẹ́ẹ̀ ni àwa ò ní nkan-kan-‘ṣe pẹ̀lú Nàìjíríà.
Màmá ní a ò fẹ́ mọ b’óṣe-jẹ́ tí wọ́n fi wà ní àtìmọ́’lé tàbí ọgbà-ẹ̀wọ̀n, gbogbo wọn pátá ni wọ́n máa gba ìtúsílẹ̀.
Yàtọ̀ sí títú gbogbo wọn sílẹ̀, àwọn ọmọ Yorùbá tí ó bá wà láarín wọn, ètò ti wà nílẹ̀ fún wọn, ó ní bí Orílẹ̀-Èdè wa ṣe máa gbé ètò yẹn kalẹ̀.
Ṣé a mọ̀ pé àwọn kan tí ńṣe lòdì sí òmìnira Yorùbá, irúfẹ́ àwọn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á lọ rọ́pò àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n bá ti tú sílẹ̀ ní Ọgbà Ẹ̀wọn!
Ẹni a wí fún, ọba jẹ́ ó gbọ́, ṣé a rí gbogbo àwọn tó ti ńdá ọ̀ràn lòdì sí àwa ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) àti lòdì sí Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), irúfẹ́ wọn ni ó máa lọ rọ́pò àwọn tí wọ́n máa túsílẹ̀ nígbàtí Ìṣàkóso-Adelé wa bá ti wọ oríkò-ilé-iṣẹ́ ìṣàkóso wa gbogbo ní ilẹ̀ Yorùbá.