Iṣẹ́ ni oògùn ìṣẹ́, ìgúnpá sì ni ìyékan ẹni. Ní Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) àlàkalẹ̀ ètò ìṣèjọba tí Olódùmarè fún màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla kò fi àyè gba ọ̀lẹ rárá.

Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ wípé, kò ní sí ọ̀lẹ ní ilẹ̀ Yorùbá, gbogbo wa ni a máa ṣiṣẹ́ tí a sì máa lówó lọ́wọ́.

Ibi tí oníkálukú bá ti kún ojú òṣùwọ̀n ni yóò ti ṣiṣẹ́, tí yóò sì máa gba owó gidi ní ọ̀sẹ̀ méjì-méjì. Orílẹ̀ èdè D.R.Y kò fàyè gba ìwà ìmẹ́lẹ́, màmá wa MOA fi yé wa wípé, kò sí ohunkóhun nílẹ̀ mọ́.

Nítorí náà, gbogbo wa ní láti ṣiṣẹ́ kí Orílẹ̀ èdè wa lè gòkè àgbà, kí ògo tí Olódùmarè fún àwa ìran Yorùbá sì leè búyọ.