Ní ìgbà àtijọ́, àwọn ọba ní olórí ìjọba ní ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n nṣe àkóso ìlú ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè wọn. Láti inú irú ìṣàkóso yí ní a tí mú ọ̀rọ̀ “Ìjọba” jáde tí ó túmọ̀ sí àjọ àwọn ọba tàbí ìgbìmọ̀ àwọn ọba.
Kí àwọn òyìnbó amúnisìn tó dé, ní ilẹ̀ Yorùbá tí ní ètò ìṣàkóso ìlú pẹ̀lú ìlànà Aláṣẹ, àwọn Aṣòfin àti ètò Ìdájọ́. Nígbàtí àwọn òyìnbó amúnisìn náà dé, wọ́n bá wa ní Orílẹ̀ èdè aṣèjọba ara ẹni
Àwọn ọba ìgbà náà mọ ẹ̀tọ́ àti ètò ìṣèlú, lóòtọ́ àwọn àìṣedédé kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ wọn, lára àwọn àṣìṣe àwọn ọba yí ní mímú ni lẹ́rú, títa àti ríra ènìyàn lẹ̀rú, yálà àjèjì tàbí ará ilú wọn.
Àwọn ọba ayé ìgbà yẹn ní ìpayà díẹ̀ fún àwọn ará ìlú, bí nkan kò bá lọ dédé ní ìlú, wọ́n à gbé ìgbésẹ̀ àtúnṣe nítorí ìbínú àwọn ará ìlú, pàápàá jùlọ àwọn ọ̀dọ́.
Tí kò bá wá sí ọ̀nà àbáyọ, ọba lè lọ ṣí’gbá fúnra ẹ̀, tàbí kí àwọn àgbàgbà ilú ní kí ó ṣí’gbá, èyí túmọ́ sí pé kí ọba pa ará ẹ̀, nítorí kí ìlú má bàjẹ́ lórí ẹ̀.
Inú òwò eru yìí ni àwon aláwọ̀ funfun náà bá àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá, ti wọ́n sì darapọ̀ pẹ̀lú wọn láti máa fi ènìyàn ṣe pàṣípàrọ̀ fún agbòòrùn, dígí, ọtí òyìnbó , àtíkè ojú àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ẹ̀rú yii ni àwọn òyìnbó nkó lọ sí ìlú aláwọ̀ funfun láti lọ jìya nípa bí wọ́n ti nfi àwọn ẹrù náà ṣiṣẹ́ agbára, láì bìkítà fún Ìlera tàbí ẹ̀mí wọn. L’átara ìbádòwòpọ̀ yi ní ìmúnisìn tí wọlé, ni àlàbọrùn bá di ẹ̀wù sì ọrùn ilẹ̀ Yorùbá.