Olódùmarè fi ohun gbogbo kẹ́ ìran Yorùbà.
Ó fi ilẹ̀ tó ṣe iyebíye ṣe àǹfààní fún àwa ọmọ aládé láti ma jẹ àǹfààní àwọn èso àti irúgbìn loríṣiríṣi, èyí tí irú rẹ̀ ṣọ̀wọ́n níbikíbi ní àgbáyé.
Ní kété tí àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso D.R.Y, wọ́n ma ṣe àtìlẹ́yìn fún wa láti ṣe àmúlò ilẹ̀ ọlọ́ọ̀rá wa.
Ọmọ Yorùbà ìrọ̀rùn ti dé, ìtura ti dé, ẹ̀mí gígùn ti dé.
Orin ìwúrí fún àwọn àgbẹ wa:
Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ ilẹ̀ wa
Ẹni kò ṣiṣẹ́ á má jalè
Ìwé kíkọ́ láì sí ọkọ́ àti àdá
Koi pé o, koi pé o