Tani ó gbìyànjú rẹ̀ rí, tó ríi ṣe? KÒSÍ!
Tani ó dojú ìjà kọ Olódùmarè, tó ríi ṣe? KÒSÍ.
Afẹ́fẹ́ ti fẹ́, a ti rí fùrọ̀ adìyẹ, aṣọ ti ká lójú eégún àwọn amoòkùn ṣìkà, Olodumare ti tú àṣírí ìpàdé ìkọ̀kọ̀ àwọn kan tí wọ́n ńpè ara wọn ní ọba ní ilẹ̀ Yorùbá, bẹ́ẹ̀ gbogbo àgbáyé ló ti mọ̀ pé kò sí ọba kankan ní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y kò ní ọba, ṣùgbọ́n àwọn tó ń pe’ra wọn ní ọba ti d’ojú ìjà kọ Olódùmarè, wọ́n sì ma parun! Wọ́n ti kọjá àyè wọn, òjò ìdájọ́ Olódùmarè ti rọ̀ lé wọn lórí.
Nínú ọ̀rọ̀ tí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, bá gbogbo àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti D.R.Y sọ̀ ní àìpẹ́ yí, ni àṣírí ti tú, pé àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ni ọba ti sọ pé kò sí nkan tó ṣe ọmọ Yorùbá, kàyéfì ló jẹ́ bí wọ́n ṣe sọ pé ìyà kò jẹ ọmọ Yorùbá.
Ẹ̀yin tí ẹ ń pe ara yín ní ọba wọ̀nyí, ayé yín ti parẹ́, alálẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá ti kọ ẹ̀yìn sí yín, ìṣẹ̀dálẹ̀ ọmọ Yorùbá tí ẹ purọ́ mọ́ pé wọn kò sọ pé ìyà ńjẹ àwọn, á ṣe ìdájọ́ fún yín, ìparun dé bá yín.
Ẹnu tí ẹ fi pa irọ́ yẹn, kí ẹnú náà kí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹrà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.
Màmá wa, MOA, ti jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn ìpàdé tí ẹ ńṣe! Ìpàdé òfò, ìpàdé àdánù, ṣé ènìyàn tilẹ̀ ni yín ṣá? Ẹ̀yin ẹranko, tí ẹ sọ pé ìyà kò jẹ ọmọ Yorùbá, tí ẹ ńgbèrò ikú sí Màmá wa, Ìránṣẹ́ Olódùmarè, Olóyè Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ẹni tí
Ọlọ́run Olódùmarè rán láti kó àwa ọmọ Yorùbà kúrò lóko ẹrú tí àwọn bàbá yín akótilétà tàwá sí, nítorí dígí, ọtí, agboòrùn, ife, wọ́n ta àwọn bàbá àti ìyá wa lẹ́rú fún àwọn òyìnbó amúnisìn.
Àwọn ìkà, olè onímọ̀tara ẹni nìkan, fẹ́ kí ìran Yorùbá tẹ̀síwájú lábẹ́ oko ẹrú ètò àwọn òyìnbó amúnisìn, tí wọ́n ńpè ní aríremáṣe nàìjíríà tí kìí ṣe ìlú, tí kò sì jẹ́ orílẹ̀ èdè. Ẹ̀yin ẹranko aláìníyè wọ̀nyí, tí ẹ pe ara yín ní ọba, ikú tí ẹ rò sí olùgbàlà wa, Màmá Ìran ọmọ Yorùbá, kí ikú yẹn jẹ́ ti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ńpe ara yín lọ́ba.
Ẹ̀yin ọ̀tá inú ilé tí ẹ ń pe ara yín lọ́ba kó’ra yín jọ, ẹ sọ pé àwọn ọmọ Yorùbá ti ńjìyà láti ọjọ́ pípẹ́, wọ́n mọ bí wọ́n ṣe ńbá ìyà náà yí, à! ẹ ti ṣìṣe! Ẹ̀yin fún’ra yín ni ẹ ṣe ìdájọ́ ara yín o! Fún ra olókùrùn ló fi ẹnu ara ẹ̀ pe ikú. Ẹ̀yin ni ẹ yan ìparun fún ara yín.
Nítorí pé ẹ lòdì sí Olódùmarè, ìparun ti dé báa yín. Nítorí pé ẹ lòdì sí iṣẹ́ tí Olódùmarè fi rán màmá wa MOA sí àwa ọmọ Yorùbà, ìparun ti dé báa yín. Nítorí pé ẹ lòdì sí Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ìparun ti dé báa yín. Nítorí pé ẹ lòdì sí Indigenous Yorùbá People (I.Y.P), ìparun ti dé báa yín.
Ikú tí ẹ ńgbèrò rẹ̀, kí ó jẹ́ tiyín! Ikú tí ẹ fi ńlé màmá wa MOA yẹn, ló ma pa gbogbo yín láìpẹ́.
A tilẹ̀ gbọ́ pé ìkan nínú yín sọ pé òun ṣetán láti fi ọmọ òun rúbọ nítorí ọ̀rọ̀ yí, kí òun ṣáà máa jẹ́ ‘ọba’; àà! Inú iná ni gbogbo yín máa ṣègbé sí!
Ẹ kú oríburúkú yín o, ṣùgbọ́n IKÚ tí ẹ ńpète-pèrò ẹ̀ yẹn, Ó DI TIYÍN LÓNI. Àṣẹ gùn-ún.
Ẹ wá gbọ́ o! Ẹ TI KÓBÁ ARA YÍN! Fídíò ìpàdé tí ẹ ṣe, àṣírí ẹ̀ ti tú.
Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí ń kí ayé pé ó dìgbóṣe o! Nít’orí ikú tí ẹ ńgbèrò sí ìyá ìran ọmọ Yorùbá, ẹ̀yin ni IKÚ náà ma pa tọmọtọmọ.
KÒ SÍ ỌBA NÍ D.R.Y, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ẹnikẹ́ni lè ṣe sí èyí.