Oore ńlá tí ìran Yorùbá kò ní gbàgbé láéláé ní Olódùmarè ṣe fún wa nípasẹ̀ màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) tí
Olódùmarè lò láti gbà wá kúrò lóko ẹrú, pẹ̀lú àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí yóò mú kí gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) máa gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn.
Gẹ́gẹ́bí MOA ṣe sọ, kété tí ọmọ tí ó jẹ́ I.Y.P ti D.R.Y, bá ti pé ọmọ ọdún mọ́kanlélógún, orílẹ̀-èdè D.R.Y yíò fún-un ní ilẹ̀. Ọ̀fẹ́ ni ilẹ̀ náà. Kíkọ́ ilé sí orí ilẹ̀ náà kò sì ní mú ìnira dání fún ọmọ náà, torí D.R.Y máa ṣe ètò tí kò fi ní nira.
A ò nílò láti rí ẹnikẹ́ni ní ìkọ̀kọ̀ kí a tó gba ẹ̀tọ́ wa ní orílẹ̀-èdè D.R.Y, níwọ̀n ìgbà tí a bá ti jẹ́ ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti D.R.Y. Ìlú yíówù tí a bá wà ní orílẹ̀-èdè D.R.Y, ẹ̀tọ́ wa yíò tẹ̀wá lọ́wọ́ nítorí pé ọ̀kan náà ni gbogbo wa. Kò sí ìpínyà. Àparò kan kò sì ga ju’kan lọ.
Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa ní gbogbo ìgbà, fún oore rẹ̀ láyé wa.
MOA ti sọ fún wa wípé, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé oore tí Olódùmarè ṣe fún wa yí, lójoojúmọ́ ní kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè kí a sì máa sìn-ín. Kí a tún fi kọ́ àwọn ọmọ wa pàápàá láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run wa nígbà gbogbo.Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè mi, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).