Nígbà àjoyọ̀ àjọ̀dún ọdún kejì ìfitónilétí gbígba ohun ìní wá padà, tí a ṣe ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Ọ̀pẹ ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún ni màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) tú àṣírí ìpàdé ọ̀tẹ̀ tí àwọn ọmọ àlè Yorùbá kan ń ṣe láti dojú ìjà kọ Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y).
Àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyí ṣe ìpàdé ìkọ̀kọ̀ náà nígbàtí wọ́n ti bá ìjákulẹ̀ pàdé nínú gbogbo akitiyan wọn láti da ìrìn àjò òmìnira wa rú, ṣùgbọ́n tí Olódùmarè ti jù wọ́n lọ, tí ìrìn àjò wa ti yọrí sí òmìnira ilẹ̀ Yorùbá kúrò nínú oko ẹrú àwọn òyìnbó amúnisìn àti apanijayé nàìjíría.
Nígbàtí wọ́n ríi pé ilẹ̀ Yorùbá ti di orílẹ̀-èdè olómìnira aṣàkóso ara ẹni, àwọn ènìyàn ìkà náà wá bẹ̀rẹ̀ síí halẹ̀ nínú ìpàdé ọ̀tẹ̀ wọn pé ọmọ Yorùbá ni àwọn náà jẹ́, gbogbo wọn ní àwọn jọ ni D.R.Y, pé àwọn náà ní ẹ̀tọ́ àti àṣẹ níbẹ̀.
Màmá wa sọ gbangba pé wọn kìí ṣe ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P), nítorí àwọn alábòsí náà ṣiṣẹ́ lòdì sí ìrìn àjò òmìnira wa.
Títí ta fi di orilẹ̀ ède olómìnira aṣàkóso ara ẹni, ṣe ni àwọn ènìyàn búburú náà nṣiṣẹ́ tako gbogbo àṣeyọrí wa, àti pé àwọn òbàyéjẹ́ náà faramọ́ ètò àwọn òyìnbó amúnisìn tí kìí ṣe ìlú, tí kìí ṣe orílẹ̀ èdè, tí wọ́n ń pè ní apaniṣayọ̀ nàìjíríà.
Màmá wa MOA tún ní àwọn ọ̀bàyéjẹ́ náà npariwo ẹnu pé bí Adelé wa bá ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní kíkún, awon máa da gbogbo rẹ̀ rú ni, àwọn ma jà ni, àti oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ àti ètò búburú lẹ́nu wọn.
Ṣùgbọ́n ìkìlọ̀ jáde láti ẹnu ìyá wa ìrọ̀rùn ló bá dé, MOA pé gbogbo ìpàdé tí wọ́n nṣe pẹ̀lú ìkásílẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn lò wà ní ìpamọ́ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí tó dájú nígbàtí ẹjọ́ wọn bá bẹ̀rẹ̀.
Màmá wa tún fi yé àwọn ẹni ibi náà pé wọ́n ń tan ara wọn jẹ ni, wọn ò bá wa ni D.R.Y, àwa I.Y.P tòótọ́ tí kìí ṣe ọ̀dàlẹ̀ ni a jọ ni D.R.Y.
Ìsọkúsọ tí wọ́n nsọ nínú ìpàdé wọn pé àwọn kò ní gba àlàkalẹ tí Olódùmarè gbé lé màmá wa MOA lọ́wọ́, àwọn máa kọ ìwé òfin ti wọn ni, ìhàlẹ̀ lásán ni tíkò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá, òfo lórí òfo pátápátá ni.
MOA wá kìlọ̀ fún àwọn ọ̀daràn náà pé àyè kò ní sí fún irú ètò òṣèlú ẹ̀tànjẹ àti olè tí àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà dúró lé.
Kò lè ṣiṣẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Yorùbá. Kí wọ́n gba nàìjíríà lọ. Àwa I.Y.P ti D.R.Y kò ní fi àyè sílẹ̀ fún ohunkóhun láti da ìpìlẹ̀ kẹta yìí wó.
Àlàkalẹ̀̀ tí Olódùmarè gbé lé màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) lọ́wọ́ fún ìran àwa ọmọ Aládé kò ní yẹ̀ rárá. Orí rẹ̀ ni ìṣàkóso orílẹ̀-èdè D.R.Y ma dúró lé títí láé.