ÀDÚRÀ: OLÓDÙMARÈ, ALÁGBÁRA TÍ Ó GA JÙLỌ, PA GBOGBO Ọ̀TÁ RUN ÀTI ALÁBỌ̀DÈ LÁARIN D.R.Y, TÍ WỌ́N NPÈTE LÁTI LO ÀWỌN TÓ PERA WỌN LỌ́BA LÁTI ṢE ÌPINYÀ-ÌKÓNILẸ́RÚ LÁARIN I.Y.P, TÍ WỌ́N NPÈTE ÀÌṢỌ̀KAN LÁARIN I.Y.P.

GBOGBO ÀWỌN TÓ NGBÈRÒ ÌKÓNILẸ́RÚ, ÒṢÌ, EBI ÀTI ÀÌNÍRÈTÍ FÚN I.Y.P TI D.R.Y, YÍÒ PARUN LẸ́SẸ̀KẸSẸ̀.

GBOGBO ÀWỌN TÓ NPÈTE ÌṢUBÚ FÚN ÌJỌBA ADELÉ D.R.Y, YÍÒ PARUN PÁTÁPÁTÁ.

OLÓDÙMARÈ, PA WỌ́N RUN, ÀWỌN TÍ WỌ́N NFI AHỌ́N-IBI PE D.R.Y NÍ ARA ÈTÒ-AMÚNISÌN NÀÌJÍRÍÀ.

ẸNIKẸ́NI TÍ Ó NPÈTE LÁTI GBÀBỌ̀DÈ FÚN I.Y.P, D.R.Y ÀTI FÚN ÀWỌN ÀLÀKALẸ̀-ÀTỌ̀RUNWÁ WA, YÍÒ DI ALÁÌSÍ, LẸ́SẸ̀KẸSẸ̀, NÍ ILẸ̀ ALÀÀYÈ YÍ, NÍPÁ AGBÁRA-GIGA-JÙLỌ OLÓDÙMARÈ.

Ọjọ́ ti pẹ́ tí ìran Yorùbá ti ń j’ìyà nípasẹ̀ àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní aṣíwájú tàbí àwọn tí a tún le pè ní adarí ilẹ̀ Yorùbá. Ṣùgbọ́n Olódùmarè wá sọ wípé ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yìí ni kí a padà sí orírun wa kí a sì kúrò nínú ìyà àti òṣì.

Ìdí nìyí tó fi gbé màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla dìde, Ó sì fún wọn ní àlàkalẹ̀ ètò ìṣèjọba tí yóò mú ìdẹ̀rùn bá gbogbo ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y).

Ní kété tí àwọn adelé wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa, láti máa tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún, ètò ìgbé ayé ìrọ̀rùn ti wà lọ́kan-ò-jọ̀kan fún t’èwe t’àgbà ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y).

Gbogbo àwọn ọ̀dọ́ wa ni yóò ní iṣẹ́ tó dára. Bẹ́ẹ̀ sì ni ẹnìkọ́ọ̀kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ọdún mọ́kànlélógún yóò ní ẹ̀tọ́ sí ilẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, ìjọba D.R.Y yóò sì tún ṣe àtìlẹ́yìn fún wọn láti kọ́ ilé náà, ṣùgbọ́n ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) nìkan ni.

Gbogbo wa ni a ní ẹ̀tọ́ sí oúnjẹ tó dára lásìkò, ìwòsàn ọ̀fẹ́, àyíká tó dùn ún wò, ilé ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Kò sí I.Y.P tí yóò tún ṣe ẹrú mọ́, àfi àwọn tí ìdílé wọn bá ti dalẹ̀ ọmọ Yorùbá nìkan. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi ọwọ́sow’ọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adelé wa, kí a sì yàgò fún ohunkóhun tó lè mú ìfàsẹ́yìn bá orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y).