Ní orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ètò ìgbáyé gbádùn lorísìírísìí ló wà fún gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P), bí ó ti wà fún àwọn arúgbó bẹ́ẹ̀ ló wà fún ọ̀dọ́, àwọn èwe pàápàá kò gbẹ́yìn.
Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé, ìyá èwe ìrọ̀rùn lóbádé ni Olódùmarè lò láti gba ìran Yorùbá kúrò lóko ẹrú, Màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin).
MOA kò fi ọ̀rọ̀ àwọn èwe ṣeré rárá, ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé ètò ìgbádùn tó ti wà nílẹ̀ fún àwọn èwe ní orílẹ̀ èdè D.R.Y lọ́kan-ò-jọ̀kan ni.
Gẹ́gẹ́ bí MOA ṣe máa ń sọ pé, láti inú oyún ni ìgbádùn náà yóò ti bẹ̀rẹ̀. Gẹ́rẹ́́ tí aláboyún bá ti fi tó àwọn ẹ̀ka ìtọ́jú aláboyún ní D.R.Y létí ni wọn yóò ti tẹ̀’wọ́ gbàá tí ìtọ́jú àti ìgbádùn yóò sì ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu.
Ṣé a rántí pé MOA tí ní kí a lọ máa bí’mọ síi?
Kò sí òbí tí kò ní rí oúnjẹ tó dára fún àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí pé gbogbo wa ni a máa ní iṣẹ́ lọ́wọ́, oúnjẹ yóò sì pọ̀ yanturu ní orílẹ̀ èdè wa pẹ̀lú owó péréte.
MOA náà sì tún ti jẹ́ kó yé wa pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ kò ní ààlà, ṣùgbọ́n yóò wu àwọn kí I.Y.P máa fẹ́ I.Y.P.
Ṣé a mọ̀ wípé I.Y.P tí ó bá fẹ́ àjòjì, àǹfààní apá kan ni àwọn ọmọ rẹ̀ yóò ní, ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé I.Y.P ni àwọn méjèèjì, ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ni àwọn àǹfààní tí yóò wà fún àwọn ọmọ wọn gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P).
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè fún àánú Rẹ̀ lórí wa. Ọmọ Aládé ti bọ́ kúrò nínú ìyà, ìgbádùn ló kù fún wa.
Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè mi, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).