Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) yóò jẹ́ orílẹ̀ èdè tí yóò fi ìdí òdodo múlẹ̀. 

Nítorí màmá wa olóyè ìyá-ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá jẹ́ màmá òdodo, wọ́n fi ìpìlẹ̀ kẹ́ta yìí lé lẹ̀ lórí òdodo.

Ìdí nì yí tí gbogbo I.Y.P ti D.R.Y ní láti fi ọkàn bálẹ̀ pé kò ní sí ìrẹ́jẹ, ìtẹ̀’tọ́ ẹni lójú mọ́lẹ̀ tàbí ìfọwọ́ọlá gbà ni lójú. Kò sí àyè láti lo agbára, ipò, owó, ọlá tàbí mímọ ènìyàn fún ìyànjẹ láti gbé ẹ̀bi fún aláre, tàbí àre fún ẹlẹ́bi.

Ètò ìdájọ́ D.R.Y yíó jẹ̀ òtítọ́ àti òdodo tó nfi ọkàn ará ìlú balẹ̀ pé kòsí ẹrú tàbí ìmúnisìn ní orílẹ̀ èdè Yorùbá. Ipele kannaa ni gbogbo ènìyàn yíó wa lábẹ́ òfin Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, (Democratic Republic of the Yoruba D.R.Y).

Màmá wa onínú’re tí jẹ́ kí a mọ̀ dájú pé èdè wa tó jẹ́ Yorùbá ni a ó fí kọ ìwé òfin orílẹ̀ èdè wa lọ́nà tí yíó fí yé wa dáradára, kí ó lè rọrùn fún gbogbo wa láti túmọ̀ rẹ̀ láì sí ìnira tàbí àlùmọ̀kọ́rọ́í kankan.

MOA tún ṣàlàyé pé èdè Yorùbá ni a ó ma lò ní gbogbo ilé ẹjọ́ wa fun ìgbẹ́jọ́ àti ìdájọ́. Nítorínáà, màmá wa MOA ti sọ fún gbogbo àwọn amòfin àti adájọ́ ní D.R.Y kí wọ́n lọ kọ́ èdè Yorùbá dáradára.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá D.R.Y

A kò lè tìtorí pé omi pá ẹnìkan lórí, kí a má mu omi mọ́