ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ni a gbọ́ pé ó ti nṣẹlẹ̀ o! nṣe ni wọ́n nba agbègbè ibẹ̀ jẹ́! àwọn òyìnbó china àti àwọn tí wọ́n npera wọn ní “ọmọ onílẹ̀” ni a gbọ́ pé nṣe ni wọ́n nwà yẹ̀pẹ̀ olówó-ìyebíyè, àti alùmọ́nì ilẹ̀ YORÙBÁ, ní ọ̀nà àìtọ́?!

Eléyi kò le ṣe kó má rí bẹ́ẹ̀! – ṣebí èyí tí ó pera rẹ̀ ní gómìnà tí kìí sìí ṣe gómìnà, ní ìpínlẹ̀ ògùn, èyíinì, ajẹgàba Dàpọ̀ Abíọ́dún, ẹni tí ayé àti ọ̀run ti bínú sí, tí ó sì máa rọ́ràn láìpẹ́ láìjìnà sí àkókò yí, ṣebí ọ̀nà àìtọ́ ni òun náà fi npe ara rẹ̀ ní gómìnà ní ìpínlẹ̀ ògùn, èyí tí ó jẹ́ ilẹ̀ democratic republic of the yoruba (D.R.Y.)

Ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, òun ni orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ti ṣe ìkéde òmìnira wa kúrò nínú àkójọpọ̀ nàìjíríà, àdàmọ̀di ètò, tí ó jẹ́ ètò ìkónilẹ́rú, ètò àwọn amúnisìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Láarin oṣù ọpẹ́, ẹgbàá-ọdún, ó lé méjílélógún, títí di oṣù ṣẹ́rẹ́, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́talélógún, ni a fi ìwé ìfitónilétí (Notification) ṣọ́wọ́ sí gbogbo gómìnà nàìjíríà tí ó wà ní ilẹ̀ yorùbá, tí a sì fi yé wọn pé lórí ìkéde ÒMÌNIRA èyí tí a ti ṣe ní ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún ni a dúró lé, àti pé kí wọ́n jọ̀wọ́ gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti ìṣàkóso, tí ó wà ni àwọn ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan náà, nítorí pé a ti dé, gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè OLÓMÌNIRA aṣàkóso-ara-ẹni Yorùbá (D.R.Y) láti gba ohun tí ó jẹ́ tiwa.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates

Aṣiwèrè tí ó njẹ́ Dàpọ̀ Abíọ́dún yí, wà lára àwọn tí a fi ìwé náà ṣọwọ́ sí, nígbànáà! tí ó sì buwọ́lùwé pé ìwé tí a fi ránṣẹ́ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ẹni tí ó jẹ́ Gómìnà Nàìjíríà, èyí tí a ní kí ó bọ̀wọ̀ fún òfin-àgbáyé, kí ó jọ̀wọ́ gbogbo ohun ìṣàkóso fún orílẹ̀-èdè D.R.Y, èyí tí kò sí nínú aríremáṣe nàìjíríà mọ́! Lẹ́yìn tí wọ́n ti buwọ́ lùwé níbẹ̀ pé àwọn rí lẹ́tà wa gbà, ṣùgbọ́n Dàpọ̀ Abíọ́dún yí jóko pa síbẹ̀ láì gbé ìgbésẹ̀ àti jọ̀wọ́ àwọn ohun-ìṣàkóso ní ìpínlẹ̀-ogùn, fùn D.R.Y, títí tí ọdún kan fi pé, tí ó tún lé, èyí tí ó sì ní ìtumọ̀ labẹ́ òfin!

Lẹ́yìn eléyi ni orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (D.R.Y) ṣe ìpolongo ìṣàkóso-ara-ẹni, ní ọjọ́ kéjìlá oṣù-igbe ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, tí a sì ṣe ìbúra-wọlé fún OLÓRÍ-ìṣàkóso-adelé wa, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Síbẹ̀, ajá Dàpọ̀-Abíọ́dún tó fẹ́ sọnù, ni kò fi gbọ́ fèrè-ọdẹ, nṣe ló pàpà jóko ìjóko-aláìgbọ́nrán sí bẹ̀. Ẹni tí ó máa tẹ́ láìpẹ́-láìjìnà! Àìkúrò lórí ibi tí ó jóko sí, kí ìṣàkóso-adelé D.R.Y ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ògùn, òun ni ó fa kí àwọn wèrè ọmọ china ó máa ṣe gbogbo ìṣekúṣe àti ìwàkuwà tí wọ́n nwa yẹ̀pẹ̀-àlùmọ́nì káàkiri ìpínlẹ̀ ògùn báyi, lọ́nà tí kò tọ́, àti lọ́nà tí ó léwu gidi fún àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) tí wọ́n ngbé ní ìpínlẹ̀ Ògùn, D.R.Y. 

Dàpọ̀ Abíọ́dún, yé kọ etí-ikún sí lẹ́tà, ìwé-ìgbàpadà, tí a ti fún ẹ, ó ku díẹ̀ kékeré kó pé ọdún méjì, báyi, tí o ti gba lẹ́tà yẹn-n?! Ẹni a bá nbáwí, tó nwa’rùn kì, ó ṣe tán àti parun. kílódé tí o ya ọmọ-àlè báyi? Àmọ́ ṣá o! o ò ní pẹ́ kábamọ̀ ìwà agidí àti ìjẹgàba tí o nhù lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba yí. ìgbà-díẹ̀ báyi lókù!

Àgbàrá tó léwu gidi ni àwọn aninilára china ndásílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀-Ògùn yí látàrí wíwa-yẹ̀pẹ̀ ní ọ̀nà àìtọ́. A gbọ́ pé àwọn olóríburúkú, ọ̀bàyéjẹ́, tí wọ́n npera wọn ní ọba, ni wọ́n nṣe onígbọ̀wọ́ fún àwọn àjèjì-aninilára wọ̀nyí! AYÉ àwọn yẹn ti bàjẹ́ ná, bẹ́ẹ̀ náà ni kò sì sí nkan tó njẹ́ ọba, mọ́, ní orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (D.R.Y) 

A gbọ́ bákan-náà, pé àwọn ajẹgàba ọlọ́pa nàìjíríà ni wọ́n tilẹ̀ nṣọ́ àwọn àjèjì-aninilára wọ̀nyí! Ayé gbogbo yín ò níí dáà!

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates

Ọlọ́run Olódùmarè, tí ó dá wa sí ilẹ̀ Yorùbá, tí ó sì jẹ́ pẹ́ òun ni ó fi ohun àlùmọ̀ni yẹ̀pẹ̀ oníyebíye yí, jínkí àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, Á mú àwọn ìṣàkóso-adelé wa wọ inú gbogbo oríkò-ilé-iṣẹ́-ìṣàkóso wa, káàkiri ilẹ̀ Yorùbá (D.R.Y) láìpẹ́ láìjìnà. 

 Gbogbo ẹ̀yin ajẹgàba wọ̀nyí, ọjọ́ ẹ̀sín yín ti dé o!

A gbọ́ pé agbègbè Abúlé-oko, Magboro, Obáfẹ́mi Owódé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, wà lára àwọn ibi tí ìjẹgàba Dàpọ̀ Abíọ́dún ti nfi àyè gbà àwọn oníṣẹ́-ibi wọ̀nyí, tí wọ́n njí ohun ọrọ̀-ajé wa, tí wọ́n sì nba àyíká àwa ọmọ Yorùbá jẹ́. 

Àwọn tí wọ́n npera wọn ní “ọmọ onílẹ̀,” náà nfi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó nba agbègbè wa jẹ́, wọ̀nyí.

Kìí wá nṣe àwọn òyìnbó china nìkan ni wọ́n nṣe iṣẹ́ ibi yí, àwọn kan tí ìròyìn náà pè ni “ọmọ nàìjíríà” wà lára àwọn tí wọ́n nwa àlùmọ́ọ́nì-ilẹ̀ káàkiri ìpínlẹ̀ Ògùn wa ọ̀ún. A gbọ́ pé, eléyi rí bẹ́ẹ̀, pàápàá ní agbègbè tí wọn npè ni ọba àti alagada ní apá ojere ní Abẹ́òkúta.

NÀÌJÍRÍÀ, KÚRÒ LÓRÍ ILẸ̀ WA, DEMOCRATIC REPUBLIC OF THE YORUBA D.R.Y!