Ìdàgbàsókè gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ni ó jẹ ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) lógún, lábẹ́ ìṣàkóso Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá, nípasẹ̀ Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá.
Gẹ́gẹ́bí Màmá wa ti sọ, gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ni ó máa ní ìdàgbàsókè àti ìgbá’yé gbádùn. Èyí tó jẹ́ pé ibi yóò wù kí a wà, ojúlówó ohun amáyédẹrùn àti ìgbé-ayé àláfíà ni ó máa wà ní àrọ́wọ́to.
Láti mú èyí wá sí ìmúṣẹ, ipele mẹ́rin ni yóò wà nínú ètò ìdàgbàsókè káàkiri ilẹ̀ Yorùbá – ipele “Ìlú-Nlá” (Urban); “Ìlú Kékèké” (Sub-Urban); “Ìgbèríko” (Rural) àti “Ẹsẹ̀kùkú” (Sub-Rural). Bẹ́ẹ̀ ni ipele kọ̀ọ̀kan sì ní ojúṣe tirẹ̀ ní orílẹ̀-èdè D.R.Y.
Èyí túmọ̀ sí pé ipele tí àgbègbè kan bá wà ni ó máa ṣe àpèjúwe irú ohun amáyédẹrùn tí yóò wà níbẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn bí omi, títì t’ó dára, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tí ó máa wà ní’bi gbogbo.
Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, agbègbè t’ó jẹ́ pé àwọn ní wọ́n npèsè oúnjẹ fún orílẹ̀-èdè wa, ó ní àwọn ohun ìdàgbàsókè tí ó gbọ́dọ̀ wà ní’bẹ̀; agbègbè tí ó jẹ́ pé ibẹ̀ ni àwọn ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ gbogbonìṣe pọ̀ sí, ó ní bí a ṣe máa ṣe ètò ìdàgbàsókè ibẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Nípasẹ̀ èyí, Ìgbèríko ní iṣẹ́ tirẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè tí ìlú-nlá kò lè ṣe: irú ìdàgbàsókè tí ó máa mú iṣẹ́ ìgbèríko dùn-ún ṣe, nínú ìrọ̀rùn, ni ó máa wà ní’bẹ̀, yàtọ̀ sí àwọn ohun amáyédẹrùn tí ó jẹ́ kòseémá nìí gbogbo D.R.Y.
Ohun tí a ń sọ ni pé Ìgbèríko ní D.R.Y kìí ṣe oko lásán tí ènìyàn máa p’ẹ̀gàn, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ ibi àmúyangàn tí ipò rẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè kò ní ṣeé fi ọwọ́ rọ́ s’ẹ́yìn.