Gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Olóyè ìyá-ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá MOA ṣe ma nsọ wípé lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá ni àkọ́kọ́.

Nínú ohun gbogbo tí ó bá ti njáde ní orílẹ̀ èdè wa, Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, I.Y.P ni a kọ́kọ́ ní ẹ̀tọ́ si. 

Nínú ètò ọ̀gbìn Yorùbá ni àkọ́kọ́, ohun gbogbo tí a bá nṣe jáde Yorùbá ni àkọ́kọ́, ní ilé iṣẹ́ wa gbogbo Yorùbá ni àkọ́kọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

Ọjọ́ ti pẹ́ tí ìran Yorùbá ti ń j’ìyà nípasẹ̀ àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní aṣíwájú tàbí àwọn tí a tún le pè ní adarí ilẹ̀ Yorùbá. Ṣùgbọ́n Olódùmarè wá sọ wípé ní déédéé ìgbà yìí àti ní déédéé àsìkò yìí ni kí a padà sí orírun wa kí a sì kúrò nínú ìyà àti òṣì.

Ìdí nìyí tó fi gbé màmá wa MOA dìde, Ó sì fún wọn ní àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí yóò mú ìdẹ̀rùn bá gbogbo ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y).

Ní kété tí àwọn adelé wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso wa, láti máa tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún, ètò ìgbé ayé ìrọ̀rùn ti wà lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan fún I.Y.P ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y).

Gbogbo àwọn ọ̀dọ́ I.Y.P ni yóò ní iṣẹ́ tó dára. Bẹ́ẹ̀ sì ni ẹnìkọ́ọ̀kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ bá ti pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún yóò ní ẹ̀tọ́ sí ilẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, ìṣàkóso D.R.Y yóò sì tún ṣe àtìlẹ́yìn fún wọn láti kọ́ ilé náà. 

Gbogbo wa ni a ní ẹ̀tọ́ sí oúnjẹ tó dára lásìkò, ìwòsàn ọ̀fẹ́, àyíká tó dára, ilé ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Kò sí I.Y.P tí yóò tún ṣe ẹrú mọ́, àfi àwọn tí ìdílé wọn bá ti dalẹ̀ Yorùbá. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi ọwọ́sow’ọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adelé wa, kí a sì yàgò fún ohunkóhun tó lè mú ìfàsẹ́yìn bá orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y.

Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá D.R.Y

A kì í pẹ̀lú ọ̀bọ  já’ko