Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) èdè Yorùbá nìkan ni èdè gbogbo nkan tí a bá nṣe. Yálà ní ilé iṣẹ́, ní ilé ẹ̀kọ́, ní ilé ìtajà àti níbi gbogbo káàkiri ilẹ̀ Yorùbá.
Màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ti jẹ́ ká mọ pàtàkì sísọ èdè abínibí wa àti wípé, èdè ni ìdánimọ̀ ẹni, Orílẹ̀ èdè tó bá sì ti sọ èdè rẹ̀ nù, orílẹ̀ èdè bẹ́ẹ̀ ti sọ ìdánimọ̀ rẹ̀ nù.
Nítorí náà a gbọ́dọ̀ mú èdè wa ni pàtàkì. Ní ilé ẹ̀kọ́, tí a bá ń fi èdè abínibí kọ́ àwọn ọmọ ní ilé ẹ̀kọ́, yóò jẹ́ kí ó yé wọn dáadáa.
Èdè Yorùbá pọ́ńbélé ni a óò máa sọ sí àwọn ọmọ wa láti kékeré.
Màmá wa ti sọ fún wa wípé, àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́ yóò dá wa padà sí orírun wa, èyí tí èdè wa sì jẹ́ ọkàn gbòógì.
Fún ìdí èyí, gbogbo àwa tí èdè Yorùbá wa kò dánmọ́ràn tó, ẹ jẹ́ kí a lọ máa ṣe àtúnṣe, nítorí orílẹ̀ èdè D.R.Y kò ní gbà sísọ èdè mìíràn láàyè nínú gbogbo ohun, iṣẹ́, àkọsílẹ̀ tàbí àdéhùn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ní orílẹ̀-èdè D.R.Y. Èdè Yorùbá nìkan ni a óò máa sọ.
Bí a bá ṣe ń sọ èdè abínibí wa ni yóò fún èdè wa ní àpọ́nlé àti iyì káàkiri àgbáyé.