Oore tí Olódùmarè ṣe fún ìran Yorùbá yí, aò ní gbàgbé láéláé. Gẹ́gẹ́ bí màmá wa, ìyá Òmìnira Yorùbá, Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) ṣe máa ń sọ pé, à ò gbọ́dọ̀ gbàgbé oore tí Olódùmarè ṣe yí, nígbà gbogbo ni kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run wa fún àánú tí a rí gbà.

Ọmọ Yorùbá kò tún kú bí adìyẹ mọ́, ètò ìwòsàn tó péye ló wà nínú àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé fún Màmá wa MOA.

A ò ní lo ọ̀nà ti òyìnbó nìkan fún ìwòsàn ní àwọn ilé ìwòsàn wa gẹ́gẹ́ bí MOA ṣe sọ, ṣùgbọ́n a óò máa lo ìlànà Ìbílẹ̀ Yorùbá pẹ̀lú èyí tí a jogún lọ́wọ́ àwọn babańlá wa. 

Modupeola Onitiri-Abiola Blueprint for Yoruba

Oríṣiríṣi ewé àti egbò ni ó wà ní ilẹ̀ Yorùbá tí kò sí ní ibikíbi ní àgbáyé tó sì ní agbára láti wo onírúurú àìsàn tí àwọn amúnisìn gan-an kò tíì rí ọ̀nà àbáyọ sí ṣùgbọ́n tí Olódùmarè fún wa lọ́fẹ̀ẹ́ ní orílẹ̀ èdè wa. 

Gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a máa jó kí á sì máa yọ̀, nítorí pé, ọ̀fẹ́ ni ìwòsàn fún gbogbo ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P).

Kò sí pé a gbọ́dọ̀ san owó kan kí a tó leè gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn tàbí lẹ́yìn tí a bá gba ìtọ́jú tán, níwọ̀n ìgbà tí a bá ṣáà ti jẹ́ I.Y.P, ètò ìwòsàn  wà fún wa. 

Kò sí àkókò tí a dé ilé ìwòsàn tí àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera kò ní sí ní ìkàlẹ̀, kódà ọjọ́ Àìkú tó jẹ́ ọjọ́ tí gbogbo ilé iṣẹ́ gbọ́dọ̀ wà ní títì pa ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, MOA ti jẹ́ kó yé wa pé, àwọn elétò ìlera yóò máa ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ náà nítorí tí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì yóò bá wáyé, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé a ò gbàdúrà fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ máa wà ní ìmúrasílẹ̀ nígbà gbogbo. 

Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ fún Ọlọ́run wa nígbà gbogbo. Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè mi orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).

Ẹyin ní ndi àkùkọ