Ní Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), ohun gbogbo ni ètò ti wà fún, láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún tí a ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ ni àwọn adelé wa sì ti ń mú’sẹ́ ṣe  láti ríi dájú pé orílẹ̀ èdè D.R.Y di àpéwò tí àwọn orílẹ̀ èdè  káàkiri àgbáyé yóò sì máa wo àwòkọ́ọ̀ṣe wa.

Àpẹẹrẹ ni ètò ìrìnnà ojú pópó wa, ìjọba D.R.Y yóò ríi dájú pé gbogbo àwọn ojú pópó ní ìlú àti  ìgbèríko káàkiri ilẹ̀ Yorùbá ni ètò ìrìnnà ìgbàlódé yóò wà láti mú kò rọrùn fún àwọn awakọ̀ àti àwọn tó ń rìn ní ojú pópó.

Ìyàtọ̀ yóò wà ní ojú òpópó ọ̀nà ti ọkọ̀, ti alùpùpù àti ti ẹléṣẹ̀ yóò wà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀,àwọn àmì ìrìnnà ojú pópó náà yóò wà lorísìírísìí.

Èyí yóò mú ìdènà bá ìjàǹbá ọkọ̀ ojú pópó àti súnkẹrẹ-fàkẹrẹ. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ní ìwé àṣẹ ìwakọ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti wa ọkọ̀ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹni tí ọwọ́ ìjọba bá tẹ̀ yóò fi’mú  k’áta òfin.