Ètò Ẹ̀kọ́ ṣe pàtàkì ní Orílẹ̀-Èdè. Ṣebí kò sí ohunkóhun tí a lè fẹ́ẹ́ ṣe, tí kò ní síí pé, yálà a fi kọ́ ni, gẹ́gẹ́bí ẹ̀bùn àti’nú wá, tàbí a tún fi kọ́’ni náà, ní ojú ayé mbí.

Ní ayé àtijọ́, ó ní bí àwọn babanlá baba wa ṣe máa nṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ tí ẹyẹ a sì máa ké bí ẹyẹ, eku a máa ké bí eku, ọmọ ènìyàn a sì máa fọ’hùn bí ọmọ ènìyàn – àwọn iṣẹ́ bíi àgbẹ̀dẹ, ààgbẹ̀, iṣẹ́ aṣọ híhun, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti fi yé wa, pẹ̀lú  ẹ̀rí, bí àwọn òyìnbó amúnisìn ṣe yí nkan wọ̀nyí padà mọ́ wa lọ́wọ́, tí wọ́n sì pinnu pé àwọn máa mú wa ju ti ọwọ́ wa dànù, kí á sì wá gba tiwọn, èyí tí kò dára tó tiwa!

Ohun àkọ́kọ́ tí ìyá wa, Màmá Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, fi yé wa, nípa ètò ẹ̀kọ́, ni pé, èyí tí wọ́n gbà lọ́wọ́ wa yẹn, tí ó sì jẹ́ pé òun ló dara jù, a máa padà sínú rẹ̀. Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé ìrònú ti ẹ̀kọ́-òyìnbó wá sí ìṣètò ẹ̀kọ́ ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá o! Ẹ jọ̀wọ́, àrà ọ̀tọ̀ láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè ni ó mbọ̀ fún wa, ní kété tí Ìjọba wa bá ti wọlé sí gbogbo oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.

Ṣùgbọ́n, ohun kan tí a mọ̀, ni pé, kò sí owó sísan fún akẹ́kọ ní gbogbo ilé-ẹ̀kọ́ D.R.Y, láti ilé-ẹ̀kọ́ ti alákọbẹ̀rẹ̀, títí dé gbígboyè àkọ́kọ́ ní fásitì. Ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe ẹ̀kọ́-ìwádi, kọjá ipele gbígboyè àkọ́kọ́, pàápàá, ní ànfààní ẹ̀yáwó tí kò ni’ra láti san rárárá, níwọ̀n ìgbàtí ó bá ti jẹ́ ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, tí kì dẹ̀ nṣe pé bóyá ó ní ohun ibi kan tí ìdílé rẹ̀ ti ṣe sí Ìran Yorùbá, èyí ti wọ́n ti fi pàdánù ànfààní tí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá yẹ kí ó jẹ.

Bẹ́ẹ̀ náà ni Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ti fi yé wa pé gbogbo àwọn akẹ́kọ tí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ni yíò ní gbogbo ìwé tí wọ́n ní’lò fún ẹ̀kọ́ wọn, tí á ti wà lórí ẹ̀rọ ayélujára ti alágbéká ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn.

Màmá wa ti sọ fún wa, wọ́n ní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè rí tí-n-tí tí ó fẹ́ f’ara jọ èyí tí a lè rí ní ibi míràn, ṣùgbọ́n ó fẹ́ f’ara jọ́ ni; ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ohun tí ó wà nínú àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé lé Màmà wa lọ́wọ́ fún ìran Yorùbá, àti pàáppàá ní ètò ẹ̀kọ́, kò sí irúfẹ́ rẹ̀ ní’bi kankan ní àgbáyé.

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.