Nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá máa ń bá wa sọ, wọ́n ti fi yé wa pé gbogbo ńkan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọ́ ní ẹ̀kọ́ ti òyìnbó, tí wọ́n sì ń tìtorí èyí pe’ra wọn ní ‘elite,” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tí a bá ko jọ, kò kúkú ju ìdajì ojú-ewé kan ní kíkọ̀-sílẹ̀ rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà ni Màmá máa ń rán wa létí, láti ìgbà dé ìgbà, ohun tí òyìnbó-amúnisìn, Lord Macaulay sọ, ní òjì-lé-lẹ́gbẹ̀sán-ọdún, ó dín márun, nígbàtí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn pé ètò-ẹ̀kọ́ ti aláwọ̀dúdú, èyí tí a sì mọ̀ pé ti Yorùbá jẹ́ gbòógì, jẹ́ èyí tí ó rinlẹ̀ ju ti àwọn òyìnbó lọ, ṣùgbọ́n tí ọkùnrin náà sọ pé kí àwọn ó tàn wá jẹ, kí a máa rí ti àwọn t’òyìnbó pé òun ló dára ju ti’wa lọ; èyí túmọ̀ sí pé ẹ̀kọ́ tiwa dára ju tiwọn lọ, ẹ̀tàn ni pé ti òyìnbó ló dára jù.

Nígbàtí a ti wá mọ eléyi, tí Màmá wa, ẹni tí Ọlọ́run sì fi iṣẹ́ ìràpadà ìran Yorùbá rán, tún ti wá sọ fún wa pé, Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá, láti máa lò, títí ayé, jẹ́ èyí tí yóò dá wa padà sí ìṣẹ̀dálẹ̀ wa; èyí wá túmọ̀ sí pé, ètò-ẹ̀kọ́ wa ní ilẹ̀ Yorùbá kò ní jẹ́ ti ẹrú – ìyẹn ni pé, kò ní dá lórí ètò tí àwọn òyìnbó-amúnisìn gbé lé wa lọ́wọ́, ṣùgbọ́n á jẹ́ ohun tí ó tún rinlẹ̀ ju ti àwọn òyìnbó lọ.

Gẹ́gẹ́bí Màmá wa ṣe máa ńsọ, wọ́n ní àrà-ọ̀tọ̀ ni; pé bí a tilẹ̀ rí àwọn ẹyọ nkan kọ̀ọ̀kan nínú nkan tiwa tó fẹ́ f’ara jọ ti àwọn míràn, ó kàn f’ara jọ́ náà ni!

Democratic Republic of the Yoruba

A ò ní kọ́ ẹ̀kọ́ tó ńfi yé wa bí wọ́n ṣe nka ìwé nìkan, a gbọ́dọ̀ lè fi ṣe ohun pàtàkì tí á mú orílẹ̀ èdè wa dàgbàsókè.

Ẹnikẹ́ni kò ní da orí wa sí ọ̀nà àìtọ́; a máa fi làákàyè kọ́ ẹ̀kọ́, kìí ṣe kí á kàn máa ka nkan tí kò yé wa, kí á tún máa dàá sílẹ̀ l’at’ẹnu wa gẹ́gẹ́bí ẹyẹ ayékòótọ́, láì mọ ohun tí a ńsọ lẹ́nu.

Ẹ̀kọ́ tí kò ní ìtànjẹ ni ẹ̀kọ́ tí a máa ní: àwọn ọmọ wa á lè ronú dára-dára, kìí ṣe àgbérù-gbésọ̀ tí kò mú ìlọsíwájú bá’ni.

Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò ní fi àyè fún ẹ̀kọ́ tí ó ńfi ẹ̀mí àti ìrònú-ẹrú sí’ni lórí. Lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá ni Àkọ́kọ́; èyí sì máa f’ara hàn nínú gbogbo ètò ẹ̀kọ́ wa.