Lóotọ́ àti ní Òdodo, a ti dé ibi tí a nlọ – a ti di Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), a sì ti bẹ̀rẹ̀ sí lo agbára ìṣèjọba-ara-ẹni wa, láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe, ẹgbàá-ọdún, ó lé mẹ́rin-lé-lógún tí a wà nínú rẹ̀ yí, pẹ̀lú gbígbé ìjọba wa wọlé, nígbàtí a ṣe ìbúra-wọlé fún bàbá wa, Olórí-Ìjọba-Adelé; bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, tí wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu; nítorí èyí, a ti kúrò ní pé a nrin ìrìn-àjò láti di orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni; a ti wá di orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni báyi, gan-an gan.

ṣùgbọ́n a ṣì mbá ìrìn-àjò gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè, a ṣì mba lọ; kì nwá nṣe ìrìn-àjò láti di orílẹ̀-èdè aṣèjọba ara-ẹni mọ́, torípé a ti di orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni; ṣùgbọ́n nísiìyí, a ti wá wà ní ìrìn-àjò GẸ́GẸ́BÍ orílẹ̀-èdè aṣèjọba ara-ẹni, èyí tí a nrin ìrìn-àjò ayé wa gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè, lẹ́yìn tí a ti jáde kúrò nínú oko-ẹrú òyìnbó amúnisìn, tí a sì ti kúrò nínú oko-ẹrú nàìjíríà, ìlú aríre-máṣe, a ti wá nrin ìrìn-àjò ayé wa, báyi, gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè, ìrìn-àjò sínú gbogbo Ògo tí Olódùmarè ti ní fún wa, láti ìṣẹ̀dálẹ̀, pé kí á le dà bí òun ṣe fẹ́ kí a dà; kí á le rí bí òun ṣe fẹ́ kí a rí; kí á le gbé Ògo òun yọ, nígbà-gbogbo nínú ìgbésí ayé wa.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates

Àti ìrìn-àjò sínú kí a lè gba ìṣèjọba-ara-ẹni wa padà, èyí tí a ti ṣe àṣeyege rẹ̀ báyi, pẹ̀lú ìrìn-àjò àti wọ inú gbogbo ògo tí Olódùmarè ti yàn fún wa, Ìrìn-àjò náà ni gbogbo ẹ o, ṣùgbọ́n ìkan yàtọ̀, pátápátá sí ìkejì: ẹ jẹ́ kí á mọ̀, dájú, pé a ti parí ìrìn-àjò láti di orílẹ̀-èdè aṣèjọba ara-ẹni padà, èyí tí a ti jẹ́ tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó wá so wá pọ̀ mọ́ àwọn kan, tí wọ́n sọ wá ní orúkọ “Nàìjíríà;” a ti parí ìrìn-àjò tìyẹn, a ti di orílẹ̀-èdè-aṣèjọba-ara-ẹni báyi, láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún.

A ti dé ibi tí a nlọ – ṣùgbọ́n, ibi tí a nlọ, èyí tí a ti dé yí, a ṣẹ̀ṣẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò ìṣe-rere wa ni, gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè tí a ti gba ìṣèjọba-ara-ẹni wa padà.

Nítorí náà, kí gbogbo àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ó mọ ìyàtọ̀ tí ó wà nínú ìrìn-àjò méjèèjì: nínú ìrìn-àjò kíní, a ti dé ibi tí a nlọ; nínú ìrìn-àjò kéjì, ìrìn-àjò láti ipele-ògo kan sí ipele ògo tó tún ga ju bẹ́ẹ̀ lọ ni, TÍTÍ AYÉRAYÉ, gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe máa nsọ ni: èyí túmọ̀ sí pé láti ògò kan sí ògo míràn, títí àrọ́mọ-dọ́mọ wa, pẹ̀lú bí a bá ṣe ntẹ̀lé Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ìran Yorùbá nípasẹ̀ Màmá wa.

Èyí túmọ̀ sí pé a níláti jẹ́ kí ìrònú wa ó mọ̀ dájú pé a kì nṣe ajìjàngbara èyí tí ó nwá bí a ṣe máa gba ìsèjọba-ara-ẹni; rárá, a ti gba ìyẹn, a ti wá ntẹ̀síwájú, nísiìyí gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè. Ẹlòmíì á sọ pé, àwọn tó jẹgàba lórí ilẹ̀ wa yí nkọ́?

Ẹ jẹ́ kí á mọ̀ pé jíjẹgàba tí wọ́n jẹgàba, ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run máa ṣí wọn ní’dí láìpẹ́, jẹ́ ara-ìdojúkọ tí a ní, tí a sì máa bo’rí rẹ̀; ìgbà tí a bá borí rẹ̀, tí a ti lé wọn kúrò, ìgbà yẹn kọ́ ni aṣẹ̀ṣẹ̀ di orílẹ̀-èdè o! Lílé wọn jáde, èyí tí Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́, tí Ó sì ti nràn wá lọ́wọ́, láti lé wọn jáde, jẹ́ ìkan nínú àwọn ìgbésẹ̀ àti iṣẹ́ tí a nṣe gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè, kìí ṣe-é pé ìgbà tí a lé wọn jáde yẹn ni a ṣẹ̀ṣẹ̀ di orílẹ̀-èdè. Ṣé ó yé wa?

Títorí pé a jẹ́ orílẹ̀-èdè, tí a sì ti gba agbára ìṣèjọba-ara-ẹni wa padà, ní ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ọdún tí a wà nínú rẹ̀ yí, ìyẹn la fi ní Agbára láti lé wọn jáde! Nítorí náà, agbára ìṣèjọba-ara-ẹni wa, èyí ti Olódùmarè ti bá wa gbà padà ní ó-lé-ní oṣù mẹ́fà sẹ́yìn báyi, agbára yẹn ni a wá nlò báyi, láti lé wọn jáde!

Èyí túmọ̀ sí pé a ti nṣiṣẹ́ lọ, báyi-báyi, gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè! A bá ara wa yọ̀.

Àá wá pe àkíyèsí wa, nísiìyí, sí gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan tí Ìyá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, sọ ní àìpẹ́ yí: wọ́n fi yé wa pé Ìrìn-ÀJÒ kí ÌRAN WA KÍ Ó MÁṢE PARUN, òun ni gbogbo ìrìn-àjò yí.

Ẹ jẹ́ kí á ṣe àláyé rẹ̀ dáradára: kí ó le yé wa yékéyéké: Màmá wa ti fi yé wa, àwa náà sì nfi ojú wa ri, lójoojúmọ́, pé, kí ó máṣe sí ohun tó njẹ́ Yorùbá mọ́, ní orí-ilẹ̀, ìfẹ́ àwọn òyìnbó-amúnisìn ni; bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ ìfẹ́ àwọn Fúlàní; àwọn Íbò, pàápàá, ìfẹ́ wọn ni, kí ó máṣe sí ìdíwọ́ kankan fún’wọn: kí àwọn òyìnbó wọ̀nyí lè máa wọ ilẹ̀ wa bí ó bá ṣe wù wọ́n kí wọ́n lè máa wa ohun àlùmọ́ọ́nì wa bí ó ṣe wù wọ́n: ìyẹn ni àwọn òyìnbó-amúnisìn nfẹ́.

Ní ti àwọn Fúlàní, kí wọ́n lè pe gbogbo Fulani ẹgbẹ́ wọn káàkiri Áfríkà kí wọ́n wá fi ilẹ̀ wa ṣe ìbùgbé: ṣé àwọn ò kúkú ngbé ní’bi kan, níjọ́ ayé wọn; alárìn-kiri yíì náà ni iṣẹ́ wọn, kí wọ́n máa gba ilẹ̀-onílẹ̀ kiri. Ìyẹn lápá kejì.l

Níti àwọn Íbò, kí a máṣe mí; tó bá wù ká kí a kú dànù, bí a ò sì kú, kí a máṣe ráyé wá ní orí ilẹ̀-baba wa! Kíni gbogbo ìwọ̀nyí túmọ̀ sí? Láarín òyìnbó, Fulani, àti Íbò, kí Yorùbá má ṣáà ti rí ayé wá; tàbí kí wọ́n kúkú kú sọnù, kí ó máṣe sí ìràn kan ní ayé yíì mọ́ tí wọ́n npè ní Yorùbá, kí àwọn àjèjì wọ̀nyí lè jogún ilẹ̀ wa! Òun ni Màmá ṣe sọ fún wa pé Ìjà-Ìran ni eléyi, ìrìn-àjò ìran ni eléyi, ó kọjá-a pé “ebi npa wá,” “títì wa kò dára,” àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ!

Ṣé ó nyé’wa? Lóotọ́, orílẹ̀-èdè Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) máa ri dájú pé ebi kò pa ọmọ-Yorùbá mọ́! Orílẹ̀-Èdè wa á sì tún ri dájú pé ní gbogbo ọ̀nà ni ọmọ-Yorùbá máa rí ayé wá; ṣùgbọ́n ṣá, ṣé a mọ̀ pé gbogbo ìwọ̀nyẹn, bí wọ́n ṣe dára tó, èyí tí kò ní ìdí’yelé ni pé kí Ìran wa kí ó máṣe parun! A ò mọ̀ bóyá èyí yé wa tó bí ó ti ṣe yẹ kí ó yé wa!

Ó ní ìdí kan gbòógì, tí Olódùmarè fi dá ilẹ̀ Yorùbá, tó sì dá wa ní Ìran Yoruùbá, sí orí-ilẹ̀ ayé yí.

Èyí túmọ̀ sí pé, wìwà tí a wà gẹ́gẹ́bí ìran Yorùbá, ìràn tí ó yàtọ̀ sí ìran míràn; ó kọjá pé kí á kàn rí onjẹ jẹ, tàbí pé kí á kàn rí pópónà tí ó dára láti rìn: ó kọjá ìwọ̀nyẹn o! Tí ó bá jẹ́ pé, ká kàn rí onjẹ jẹ nìkan ni, tàbí kí á kàn rí títí tí a máa rìn, tàbí ilé-iṣẹ́ tí a ti máa ṣiṣẹ́, kò nílò kí Olódùmarè ó dá wa ní ìran-ọ̀-tọ̀ọ̀tọ̀!

Dídá wa ní ìràn-ọ̀-tọ̀ọ̀tọ̀ túmọ̀ sí pé ó ní nkan-kan, gbòógì, tí Olódùmarè dá Ìran kọ̀ọ̀kan kí ó wá ṣe nínú aye yí! Tí ìran kan bá sì fi àyè sílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni láti pa àwọn run, gbogbo ìran náà máa jẹ́jọ́ níwájú Olódùmarè, kílódé tí wọ́n ṣe fi àyè sílẹ̀ pé kí ìran wọn náà kí ó parun!?

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ìran tí ó bá parun, túmọ̀ sí pé apá kan Ògo-Olódùmarè nínú-ayé-yi ti parun nìyẹn! torí ó ní pàtàkì ògò kọ̀ọ̀kan tí Ọlọ́run ṣe dá Ìran kọ̀ọ̀kan – Ọlọ́run sì fẹ́ kí ògo-ìran kọ̀ọ̀kan ó wá sí ìmúṣẹ; nítorí náà, ọ̀rọ̀ yí kọjá pé kí á kàn rí onjẹ jẹ, tàbí kí ọmọ wa ó rí ilé-ìwé lọ, ó kọjá bẹ́ẹ̀.

Inkan tí ó wà nílẹ̀ ni pé kí ògo tí Olódùmarè tìtórí rẹ̀ ṣ’ẹ̀dá Ìran-Yorùbá, kí ògo náà kí ó máṣe wọlẹ̀ tìtorí pé a fún’ra wa gba ẹnikẹ́ni ní àyè láti pa Ìran wa run!

Èyí túmọ̀ sí pé tí Ìran wa bá parun, èèwọ̀, kìí ṣe ẹni tí ó pa wá run, nìkan, ni ó máa jẹ́’jọ́ níwájú Olódùmarè, àwa fún’ra wa, tí a kọ̀, tí a ò gbé ìgbésẹ̀ tí ó yẹ kí á gbé, kí a má bàá parun, tí a la ojú wa sílẹ̀, títí tí wọ́n fi pa Ìran wa run, àwa gan-an ni Olódùmarè máa béèrè àdánù-ògo tí pípa-ìran-wa-run náà, tí ó jẹ́, àwa ni Olọ́run máa bérè àdánù-ògo náà ní ọwọ́ rẹ̀: nítorí, Olódùmarè, ẹnití Ó ṣe Ẹ̀dá Ìran Yorùbá, á sọ, nínú Ìdájọ́ Rẹ̀ pé, òun fi Ìran kan sí’nú ayé yí, tí wọ́n npè ní Ìràn Yorùbá, àti pé ó ní ohun tí Òun fẹ́ kí Ìran Yorùbá yí ó jẹ́, àti kí wọ́n dà, ní Orí-Ilẹ̀ Àyé, ṣùgbọ́n àwọn Ìran yí Fún’ra wọn ni wọ́n gbàbọ̀dè fún’ra wọn!

Àwọn fún’ra wọn ni wọ́n kọ̀ tí wọn ò ṣe ohun tí ó yẹ kí wọ́n ṣe, ní àkókò tí ó yẹ kí wọ́n ṣe-é; tìtorí èyí, Ìran náà ti bọ́ sí Òkun-Ìgbàgbé, a kì yíò sì rí Ìran náà mọ́ ní sàkáání Olódùmarè, nítorí pé wọ́n gba àbọ̀dè fún ara Wọn, wọ́n sì ṣe àìgbọ́ran sí ọ̀nà tí Olódùmarè là kalẹ̀ fún wọn; wọ́n fi Ìran wọn sílẹ̀ láti jẹ́ Ìjẹ fún àwọn Ìran míràn; wọ́n sì fi àìbìkítà gba àwọn míràn láàyè láti kó wọn kúrò ní orí Ilẹ̀-Ayé, tí ó fi wá jẹ́ pé èmi Olódùmarè wá pàdánù Ìran náà, torí pé wọn sọ ohun tí mo gbé-lé wọn l’ọwọ́ nù!

Kíni ó yẹ kí á ṣe fún Ìran yí, tí ó gba ara wọn láàyè kí àwọn míràn ó pa’wọ́n run kúrò ní Orí-Ilẹ̀ Alààyè? Gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá, pátá, ní ayé àti Ọ̀run ni ó máa sọ pé Olódùmarè jàre, ìyàkíyà tí ó bá fẹ́ fi jẹ ìran náà, ìbáà ṣe nínú Sàré-è, tàbí ibikíbi tí wọn ìbáà wa!

A ò fi eléyi dẹ́rù bà wá-à, rárá! Ṣèbí àwa ni Ìran Yorùbá, ìran tí ó MỌ Olódùmarè, tí ó MỌ Ọlọ́run, tí a mọ̀-ọ́ láti inú-ìṣẹ̀dálẹ̀ wa wá; a kìí ṣe kèfèrí-ì; àwa ni Ìran tí Olódùmarè dá pẹ̀lú Ẹ̀rù Rẹ̀ ní ọkan wa, a ní Ìpayà fún Olódùmarè; àwa ni ẹni tí ó ma Àtubọ̀tán; àwa ni ẹni tí ó mọ̀ pé àṣepamọ́ ló wa, àṣegbé kan kò sí! A mọ̀, nínú Ìṣẹ̀dálẹ̀ wa, pé a ò lè fi ojú Ẹlẹ́da wa gbolẹ̀, kámári, láì-lẹ́yìn! Ìdí nìyí tí Màmá wa fi nsọ-ọ́, nígbà gbogbo pé,

Ìran-àwọn kò ní parun! Ọ̀rọ̀ yí kọjá pé kí ebi má pa wá nìkan, ó kọjá pé kí á rí òwò-àṣejèrè ṣe nìkan; ó kọjá gbogbo Ìwọ̀nyẹn! Kí Yorùbá máṣe parun mọ́ Olódùmarè lọ́wọ́; kí a má gba Ọ̀tá láàyè láti yọ-ṣùtì sí Ẹlẹ́da wa pé, Ṣé kò tán ní’dí ẹ, àwọn ìran tí O ngbé gẹ̀-gẹ̀-gẹ̀ nìyẹn, àwọn fún’ra wọn kò náání ara wọn gẹ́gẹ́bí ìwọ tí O dá wọn ṣe náání wọn; Ìwọ̀nyí ni Màmá wa nsọ, pé kí a máṣe ba ojú Olódùmarè jẹ́, kí a máṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá tí ó lòdì sí Ẹlẹ́da ìran-Yorùbá ó sọ Ọ̀rọ̀-Òdì sí Ẹlẹ́da wa tìtorí àìbìkítà tiwa: kí a máṣe jẹ́ kí Ìran Yorùbá ó parun! Nítorí, ní òtítọ́ àti ní Òdodo, ohun tí Nàìjíríà nfẹ́ nìyẹn o!

Ohun tí àwọn ọmọ Íbò tó sọ pé Ilẹ̀ wa kò sí fún ẹnikẹ́ni [no man’s land], inkan tí wọ́n nlépa ẹ̀ nìyẹn o! pé kí ìrántí Yorùbá kí ó parẹ́ ní orí-ilẹ̀ Ayé; ohun tí Fulani náà nlépa rẹ̀ nìyẹn o! tí wọ́n fi ngé’wa lọ́wọ́ gé wa l’ẹsẹ̀, nínú oko wa gbogbo, lórí Ilẹ̀ tí Olódùmarè fifún wa!

Tí àwọn ọmọ Yorùbá kan sì npàdí àpò pọ̀ pẹ̀lú wọn! – wọ́n pera wọn ní Ọba, wọ́n pera wọn ní Bọ̀rọ̀kìní, wọ́n pera wọn ní Àgbààgbà, ṣùgbọ́n ibi kí ó máṣe ti sí nkan tí ó njẹ́ Yorùbá mọ́ ní orí-ilẹ̀ ayé yí, ibẹ̀ ni wọ́n dúró sí o!

Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wèrè wọn, ọmọ-ènìyàn bí ti wọn ni wọ́n bá mu’lẹ̀ o! wọ́n ní àwọn ti mu’lẹ̀, nítorí náà, kò kàn wọ́n tí Ìran wọn bá nṣègbé, wọ́n nṣe lòdì sí ohun tí Olódùmarè nṣe, wọ́n nṣe lòdì sí ẹni tí Olódùmarè gbé dìde, wọ́n ró pé ìjà-ti-ara ni, wọn ò mọ̀ pé ìjà-ẹ̀mí ni, ìjà pé kí odindi Ìran, Ìran-Yorùbá, máṣe parun ni, kò yé wọn!

Ojú wọn ti fọ́, tàbí ó yé wọn ṣùgbọ́n àṣìtáánì tó ngbé inú-ọkàn wọn kò jẹ́ kí ẹ̀mi-ìṣerere ó le gbé ibẹ̀, torí wọ́n ti pinú pé ẹ̀dá-alààyè tí àwọn bá mulẹ̀ ni àwọn máa dúró tì! Wọ́n rí òótọ́ ní’lẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n dúró ti irọ́; tìtorí pé wọ́n ti bá irọ́-mulẹ̀; wọ́n ti gbé Irọ́ ga ju Òtítọ́ nínú Ọkàn tiwọn, wọ́n sì ti pẹ̀gàn olóotọ́!

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates

Irú nkan tí Òyìnbó Amúnisìn nfẹ́ gan-an nìyẹn o! Kí ìran-ọmọ-Aládé ó di àwátì ní ilẹ̀ Alààyè! Kí á sọ pé àwọn dà, kí wọ́n máṣe rí’wa mọ̀! Áà! èèwọ! Ohun tí wọ́n nfẹ́ nìyẹn, kí àwọn lè wá jogún ohun tí Olódùmarè jogún rẹ̀ fún Ìran Yorùbá: òun ni Màmá wa ṣe nké fita-fita, wọ́n ní ÌRÌN-ÀJÒ ÌRAN ni eléyi o, ìrìn-àjò Ẹ̀mí sì ni!

Ẹnikẹ́ni kò leè fi ara rin ìrìn-àjò náà, áá tẹ́ pátápátá, ẹ jẹ́ kí á wo ohun tí Màmá wa nfi ojú-w’iná rẹ̀, bí ẹni tí ó nrìn níbi tí angẹ́lì pàápàá ti mbẹ̀rù niì! Tàbí ojú kékeré ni a fi nwo àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n máa nj’ihìn fún wa pé àwọn ti gbé ni? Ọ̀tá pọ-ọ!

Olódùmarè fún’Ra Wọn ni ó nṣọ́ Màmá-a! Àìmoye ọ̀tá tí ó fẹ́ kí Ìran Yorùbá ó Parun! Tí àwọn tí ó rò pé kò sí b’awọn ò ṣe jẹ́ ní Ilẹ̀ Yorùbá, sì nfi ọwọ́-so’wọ́-pọ̀ pẹ̀lú wọn! Rárá o! wọn ò níí riṣe!

Ọmọ Yorùbá, ní’bo ni Ìwọ dúró sí? O wà fún Ìran rẹ àbí o dúró ti Àwọn Ọ̀tá?

Ìjà Ìran ni O! Ìrìn-àjò ìran ni! Ìtàn wo ni ìwọ nkọ sílẹ̀ nínú Ìrìn-Àjò yí? Olódùmarè fún’Ra Rẹ̀ ló wà l’ẹnu iṣẹ́! Àwọn ni wọ́n sì gbé iṣẹ́ náà lé Màmà Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, Màmá wa, lọ́wọ́: Ẹni tí Olódùmarè ti yàn, tí Wọ́n sì ti pèsè wọn sílẹ̀, pé, ní ìgbà yí, ní àsìkò yí, kí wọ́n kó Ìran-Yorùbá kúrò nínú oko-ẹrú; kìí wá ṣe kúrò nínú oko-ẹrú nìkan; ṣùgbọ́n tí wọ́n tún Wá gbé Àlàkalẹ̀ Ìṣerere Ọmọ-Yorùbá lé lọ́wọ́: Màmá sì ti wá sọ o! – wọ́n ní a ò gbọdọ̀ yọ kúrò nínú Àlàkalẹ̀ yí, bẹ́ẹ̀ ni A Ò gbọ́dọ̀ fi kun! Èdùmàrè ló fọ’hùn sí wa, Ọmọ Yorùbá! Ìfẹ́ ni Ọlọ́run ní fún wa, tí Ó fi ṣe èyí!

Ẹ jẹ́ kí á máa ránti nígbàgbogbo – Ìrìn-Àjò Ẹ̀mí ni o, Ìrìn-Àjò Ìran sì ni! ÌRAN YORÙBÁ, láyé, KÒ NÍ PARUN! Ó wà lọ́wọ́ èmi àti ìwọ: Kí Olódùmarè kí ó da ojú Gbogbo Àwọn Ọ̀tá wa bolẹ̀ – ẹ ò ní ṣe rere, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ẹ jẹ́!