Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (D.R.Y), èdè Yorùbá yóò padà sí bí ó ti wà ní àtijọ́.
Agbára tí Ọlọ́run fi sínú èdè, àdìtú ni, nítorí èdè jẹ́ ohun tí a jogún láti inú ẹ̀jẹ̀ àwọn babanlá wa gẹ́gẹ́bí Olódùmarè ṣe dá wa ní elédè Yorùbá.
Ẹ jẹ́ kí á máa fi èdè abínibí wa kọ́ àwọn ọmọ wa, á leè máa gbilẹ̀ nínú ọkàn wọn àti nínú ọpọlọ wọn. Gbogbo ohun tí wọ́n bá nfi èdè àjogúnbá wọn kọ́ wọn, á lè máa yé wọn yékéyéké.
Nítorí èdè Yorùbá jẹ́ èdè àjogúnbá wọn, kò ní là wọ́n lóogùn láti ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye rẹ̀.
Gbogbo òbí I.Y.P ẹ dẹ́kun àti máa fi èdè àjèjì kọ́ àwọn ọmọ yín, nítorí èdè Yorùbá ni ìdánimọ̀ wọn, èyí yóò sì ṣe àfihàn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti jáde wá.
Olódùmarè ló ṣe wá ní elédè Yorùbá, kò sì sí ohun tí ẹnikẹ́ni lè ṣe si, àfi kí á gbé èdè wa lárugẹ kí ó lè gbilẹ̀ káàkiri àgbáyé.
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, D.R.Y.