Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin), ẹni tí Olódùmarè yàn fún Ìgbàlà àwa ọmọ Yorùbá, fi ìmoore gbogbo ọmọ Yorùbá hàn sí àwọn tó ti nfún wa lówó títí di àsìkò yí, àti àwọn tí ó sì tún nfún wa lówó si – èyíinì, àwọn tó nfún orílẹ̀-ede wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ní owó, láti lè gbọ́ àwọn bùkátà tí ó pan-dandan, láti ìgbà tí a ti wà ní ipele ÒMÌNIRA YORÙBÁ 2022, títí di àsìkò yí tí a ti wá di orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n tí a ṣì nílò ìrànlọ́wọ́ yí, látàrí pé a ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí ní lo àwọn ohun-àmúṣọrọ̀ wa àti àwọn ilé-iṣẹ́ ìṣàkóso wa.
Ṣé a ránti pé ní àìpẹ́ ni Màmá wa MOA rọ̀ wá pé kí a ṣì máa fi owó sí àpò náà, èyí tí a mọ̀ sí “òmìnira account.” MOA ní àwọn dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tí ó ti nfi owó si. MOA sọ pé Olódùmare a máa pọ́n wọn lé, gẹ́gẹ́bí wọ́n ṣe dìde sí rírọ̀ tí àwọn rọ̀ wá láti fi owó sí àpò náà.
Màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Àaàfin), sọ pé torí pé ó rí bóṣe rí ni, wọ́n ní tó bá jẹ́ pé àwọn Adelé wa ti wọ oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso wa, kò sí nkankan tí a tún máa fi owó ẹnikẹ́ni ṣe mọ́, nítorí, gẹ́gẹ́bí ìṣàkóso orílẹ̀-èdè, kété tí a bá ti wọ Sẹkitéríátì ni a ti máà bẹ̀rẹ̀ sí níí gbé ìgbésẹ̀ tí ó máa mú owó wọlé.
Ìtọ̀nà tí a sì ní ni pé a máa ṣe ètò ìmójútó-ìlú, ìṣàkóso orílẹ̀-èdè wa, gẹ́gẹ́bí ìdókòòwò ni – ṣe bí o ṣe mọ, ẹlẹ́wà-ṣàpọ́n, a à níí kọjá-àyè wa. Abẹ́ oore-Ọlọ́run ni a ṣì máa wà – abẹ́ ìlérí Olódùmarè sí àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti D.R.Y, pé a máa yá àwọn orílẹ̀-èdè míràn lówó ni, àwa ò ní yá’wó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.
Màmá sọ pé Màjẹ̀mú Olódùmarè fún wa nìyẹn, ati pé a níláti rin ìrìn májẹ̀mú yí, kí á lè ri dájú pé a mú májẹ̀mú yẹn dání, a lòó, ó sì wà pẹ̀lú wa títí láí, pé, a ò sí lóko-ẹrú gbèsè.
Màmá ní tí kìí bá ṣe ti àwọn tí ó pe’ra wọn ní òmìrán, tí wọ́n npera wọn ní ìkà, tí wọ́n ntadí’nà, oríṣiríṣi ìgbádùn àti oore ni ó máa wà. Pẹ̀lú ẹ̀ náà, nkan tí wọ́n fi ro ibi sí wa, Màmá wa MOA ní, Olódùmarè ṣì nyọ dáradára fún wa, jáde ní’bẹ̀.
Màmá wá sọ pé, gbogbo ẹyin tí ẹ ti fi owó si, oore ni ẹ ṣe fún orílẹ̀-èdè wa o, Olódùmarè sì máa san yín ní oore yẹn. Wọ́n ní àwa náà, gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè, a máa sán fún yín.
Àfi ìwọ tí o fi owó síbẹ̀ ṣùgbọ́n tí a mú ẹ, tí a ri pé àbòsí lo nṣe. Màmá wa MOA ní gbogbo àwọn tó yá wa lówó, pátá, ó di dandan kí wọ́n jẹ èrè ẹ̀.