Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) èdè Yorùbá nìkan ni èdè ìbánisọ̀rọ̀ àti ìkọsílẹ̀ fún ohun tí a fẹ́ ṣe ní ilé iṣẹ́, ilé ẹ̀kọ́, ilé ìtajà, gbogbo ohun tí ó jẹ́ ìgbé-ìlú.

Màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ti jẹ́ ká mọ pàtàkì sísọ èdè abínibí wa àti wípé, èdè ni ìdánimọ̀ ẹni, Orílẹ̀ èdè tó bá sì ti sọ èdè rẹ̀ nù, orílẹ̀ èdè bẹ́ẹ̀ ti sọ ìdánimọ̀ rẹ̀ nù.

Nítorí náà a gbọ́dọ̀ mú èdè wa ní pàtàkì, pàápàá ni ilé ẹ̀kọ́, tí a bá ń fi èdè abínibí kọ́ àwọn ọmọ ní ilé ẹ̀kọ́, yóò jẹ́ kí ó yé wọn dáadáa.

Èdè Yorùbá pọ́ńbélé ni a óò máa sọ sí àwọn ọmọ wa láti kékeré. Àwọn àjòjì tó bá fẹ́ máa gbé ní orílẹ̀ èdè D.R.Y yóò lọ kọ́ èdè Yorùbá èyí tí kò bá gbọ́ èdè wa yóò gba ògbufọ̀.

Màmá wa ti sọ fún wa wípé, àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́ yóò dá wa padà sí orírun wa, èyí tí èdè wa sì jẹ́ ọkàn gbòógì. 

Fún ìdí èyí, gbogbo àwa tí èdè Yorùbá wa kò dánmọ́ràn tó, ẹ jẹ́ kí a lọ máa ṣe àtúnṣe.

Bí a bá ṣe ń sọ èdè abínibí wa ni yóò fún èdè wa ní àpọ́nlé àti iyì káàkiri àgbáyé.

ÌKÌLỌ̀ FÚN GBOGBO Ẹ̀YIN ÀGBẸ̀

Ẹ má ṣe gba irúgbìn GMO lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ọ̀nà míràn láti pa àwa aláwọ̀ dúdú run ni, àìsàn oríṣiríṣi ni irúgbìn yí yóò fà sí àgọ́ ara ẹnití ó bá jẹẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni náà kò ní leè bí ọmọ mọ́, àti wípé, ilẹ̀ tí wọ́n bá gbin irúgbìn yí sí yóò di aṣálẹ̀ tí kò sì ní leè mú èso jáde mọ́.

Fún ìdí èyí, ẹni tí ọwọ́ ìṣàkóso Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá bá tẹ̀, ẹ̀sùn ìpànìyàn ni ò. Nítorí náà, a rọ gbogbo ẹ̀yin Indigenous Yoruba People (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) wípé, ibikíbi tí ẹ bá ti rí ẹni tí ó bá gba irúgbìn yí tàbí ẹni tí ó fún wọn, ẹ bá wa ya àwòrán wọn, àti ẹni tí ó fún wọn, àti ẹni tí ó gbáà, apànìyàn ni àwọn méjèèjì.

Ẹ tọ́jú àwọn irúgbìn àbáláyé tó wà lọ́wọ́ yín.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal