Gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Olódùmarè tó gbé màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) dìde fún ìtúsílẹ̀ àwa ọmọ Aládé kúrò nínú ìnira.
Ní báyìí tí a ti gba agbára ìṣàkóso orílẹ̀ èdè wa padà, kò sí ìnira mọ́ fún I.Y.P kankan nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé fún Màmá wa MOA.
Gẹ́gẹ́ bí MOA ṣe sọ fún wa wípé, kò sí ṣíṣe iṣẹ́ àṣekú ní D.R.Y, dandan sì ni fún IYP láti ní àkókò ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, ó kéré tán ẹ̀ẹ̀kan sí ẹ̀ẹ̀méjì láàárín ọdún kan.
Èyí yóò fún àwa I.Y.P ní àǹfààní láti sinmi, láti tún ara wa se, àti láti dá àwọn ìlú wa ní D.R.Y mọ̀. Nítorí púpọ̀ nínú wa iṣẹ́ ni a máa ń ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún títí dé òpin ọdún, tí a kìí fi ààyè sílẹ̀ fún ìsinmi.
Ṣùgbọ́n ìgbà ọ̀tun ti dé báyìí, ọmọ Aládé ò tún ṣiṣẹ́ bíi aago mọ́, tí a bá ti ṣe iṣẹ́ fún àkókò díẹ̀, a gbọ́dọ̀ lọ fún ìsinmi.
Ẹ má gbàgbé wípé, ní àkókò ìsinmi yí, àwọn ìlú tó wà láàárín orílẹ̀ èdè D.R.Y nìkan ni a óò máa lọ ò, èyí yóò fún wa ní àǹfààní láti mọ agbègbè wa dáadáa, a sì gbọ́dọ̀ fi ẹ̀rí ránṣẹ́ sí àwọn alákòóso D.R.Y.
Olódùmarè tó wípé ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yí ni kí ìran Yorùbá padà sílé tó sì fún wa ní àlàkalẹ̀ ètò láti tẹ̀lé, fún ìgbá’yé gbádùn àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P), àsepé oore ni Ó ṣe fún wa, nítorí náà ẹ jẹ́ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá nígbà gbogbo fún oore rẹ̀ lórí ìran Yorùbá.
Lẹ́hìn òkùnkùn biribiri, ìmọ́lẹ̀ á tàn