Olódùmarè jogún ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òyé fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá nínú àwọn àgbékalẹ̀ ohun rere l’àgbááyé. Ajíṣe bíi Yorùbá làárí, Yorùbá kìí ṣe bi ẹnìkọ́ọ̀kan.

Ara ìdí nìyi tí Màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla ṣe ma nsọ wípé àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá máà rí ògo wọn lò ni Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, D.R.Y.

Àwọn ọ̀dọ́ tí àwọn arógobògojẹ́ ti yi ayé wọn padà, gbogbo wọn pátá ni orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (Democratic Republic of  the Yoruba, D.R.Y), má ṣe ìtọ́jú wọn, tí wọ́n sì máa rí ògo wọn lo.

Awọn ọ̀dọ́ tó mọ̀ nípa ìmọ̀-ẹ̀rọ, ayàwòrán, gbẹ́gilére àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, kí wọn lọ ṣe ìmúrasílẹ̀ fún àfihàn ògo wọn fún ayé rí. Gbogbo ẹ̀yin ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá, ẹ lọ ṣe àwárí ara yín, ọjọ́ ìṣelógo yin kò pẹ̀ẹ́ mọ́

Onírúurú ni àwọn àlákalẹ̀ èèto tó wà fún gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá I.Y.P pẹ̀lú èètò ìrọrùn ẹ̀yáwó fún ìrànlọ́wọ́ iṣẹ́, èètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti alákọbẹ̀rẹ̀ títí dé àkọ́kọ́gboyè Fásitì àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. 

Ògo gbogbo ọmọ aládé a búyọ ni orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, D.R.Y.