A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó fún ìran Yorùbá ní ìṣègùn lórí gbogbo àwọn ọ̀tá tó sì tú wa sílẹ̀ kúrò nínú oko ẹrú nípasẹ̀ màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tó rán sí wa tó sì fún wọn ní àwọn àlàkalẹ̀ ètò tí yóò dá wa padà sí orírun wa
Láìpẹ́ yìí tí màmá wa bá àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá sọ̀rọ̀, wọ́n jẹ́ kó yé wa wípé, èdè Yorùbá nìkan ni a óò máa sọ ní ibiṣẹ́ wa gbogbo ní orílẹ̀ èdè wa. Màmá ní nítorí náà kí gbogbo wa lọ máa kọ́ èdè Yorùbá.
Wọ́n ní òṣìṣẹ́-ìṣàkóso tí o bá sọ èdè míràn yàtọ̀ sí èdè Yorùbá ní ilé iṣẹ́, wọ́n á já ìwé-ẹ̀sùn fún ẹni bẹ́ẹ̀.
Fún ìdí èyí, a rọ gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) wípé, kí a gbọ́ ìkìlọ̀ yí, kí a máṣe kọ etí ikùn síí.
Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ wípé, ọkàn lára àwọn ìdánimọ̀ ẹni ni èdè jẹ́, nítorí náà, ó ṣe pàtàkì púpọ̀ láti máa sọ èdè wa kí a sì múu ní ọ̀kúnkúndùn.
Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti kúrò lábẹ́ àwọn amúnisìn, kò sí ìdí láti máa tẹ̀síwájú nípa sísọ èdè ẹrú, aò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ètò amúnisìn mọ́, tí a mọ̀ sí àkójọpọ̀ nàìjíríà.
Orílẹ̀ èdè aṣàkóso ara ẹni ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, a ò nílò láti yá èdè tàbí àṣà orílẹ̀ èdè kankan lò nítorí pé a jíṣe bíi Yorùbá làárí, ìran Yorùbá kò ní ṣe bí baba ẹnìkọ́ọ̀kan láéláé.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, púpọ̀ àwọn ọmọ tí ó wà ní orí ilẹ̀ Yorùbá lónìí ní kò leè sọ èdè Yorùbá látàrí ìtànjẹ àwọn amúnisìn, wọ́n sọ èdè àwọn babańlá wa di èdè àwọn ará oko.
Fún ìdí èyí, a rọ àwa òbí láti ṣe àtúnṣe kí a sì máa fi òye yé àwọn ọmọ wa, ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa sọ èdè Yorùbá pàápàá ní àkókò tí a wà yí, nítorí náà, ó ṣe kókó.
Kí Olódùmarè kí ó bùkún fún Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, D.R.Y
Bí a ò kú, ìṣe ò tán