Àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) tí Olódùmarè fún màmá wá, Modupẹọla Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin), kò fi àyè
sílẹ̀ fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí owó ẹ̀yìn rárá, yálà ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́, èka ètò ẹ̀kọ́, nínú ètò ìṣàkóso àti ní onírúurú ẹ̀ka ní D.R.Y.
Èyí yóò fún gbogbo I.Y.P ni àǹfààní láti leè kópa nínú ètò ìṣàkóso orílè-èdè D.R.Y àti láti leè lo ẹ̀bùn àmútọ̀runwá tí Olódùmarè yọ̀nda fún wọn fún ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè wa, D.R.Y.
Ẹnikẹ́ni tó bá gbìyànjú láti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí láti fún ènìyàn, ti ṣe lòdì sí àlàkalẹ̀ D.R.Y, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní lọ láì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Nítorí pé ní orí ọ̀títọ́ ni a gbé ìpìlẹ̀ wa lé, ẹni tí ó bá sì ti di ipò kan tàbí òmíràn mú ní orílẹ̀ èdè wa gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́ láì fi dúdú pe funfun fún ọmọ Yorùbá.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ fún wa wípé, àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso yí, kò sì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní àgbáyé, àti wípé àwọn nìkan ni Olódùmarè fún tì kò sì sí ẹ̀dà rẹ̀ ní ibikíbi.
Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, D.R.Y.