Ní kété tí àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìṣàkóso wa, iṣẹ́ lọ́kan-ò-jọ̀kan yóò bẹ̀rẹ̀ ní t’ìbú t’òró ilẹ̀ Yorùbá láìfi àkókò ṣòfò.

Nínú ọ̀rọ̀ tí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla (Olóyè Ìyá Ààfin) bá wa sọ láìpẹ́ yí, màmá sọ fún wa wípé a máa tún àwọn ilé ìwé wa kọ́, nítorí pé gbogbo àwọn ilé ìwé tí wọ́n rí tí àwọn ènìyàn fi àwòrán rẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn kò sì èyí tí wọ́n lè tún ṣe níbẹ̀ bíkòse kí wọ́n wo, kí wọ́n sì tun kọ́, kìí ṣe àyíká tí wọ́n ti lè kọ́ ìwé tí ìwé náà máa wọ orí, ètò ẹ̀kọ́ tí a sì fẹ́ ṣe yí, ẹ̀kọ́ náà ní láti ṣe àǹfààní ní gidi.

Gbogbo ẹ̀yin kọ́lé-kọ́lé, ẹnikẹ́ni tí o bá mọ̀ pé òhun fẹ́ gba iṣẹ́ kó mọ̀ pé òun kìí ṣe ọ̀lẹ, nítorí ó lè nílò pé kí a máa ṣe iṣẹ́ náà láì dá’wọ́ dúró, ma sọ pé iṣẹ́ náà máa gbà ẹ́ ní oṣù mẹ́fà tàbí oṣù mẹ́sàn, MOA ní pé àwọn kò ní gbà o, ṣé kí àwọn ọmọ wá jókòó sílé fún oṣù mẹ́fà ni, nítorí náà, ìwọ tóo bá mọ̀ pé oò ní lè ṣe ní páápààpá kí o tètè sún sí iwájú.

Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ wípé, a ò ní rìn rárá, ṣùgbọ́n a máa fò ni nítorí kò sí ohunkóhun ní’lẹ̀. 

Fún ìdí èyí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá iṣẹ́, iṣẹ́ máa pọ̀ gan-an ni, Olódùmarè ti ṣe ìyanu fún wa. A ti bọ́ sínú ayọ̀ àti ìdùnnú, nítorí náà kí oníkálukú lọ máa múra sílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ fún ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Ìbùkún ni fún Orílẹ̀ Èdè mi, Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá D.R.Y

Ẹni tí a ńwò kì í wò’ran