Ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) a ò ní sọ ìdánimọ̀ wa nù nítorí pé odò tí ó bá gbàgbé orísun rẹ̀, yóò gbẹ ni. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) sọ wípé, èdè Yorùbá nìkan ni a óò máa sọ ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y).
Ọ̀kan lára ìdánimọ̀ ẹni ni èdè jẹ́, nítorí náà ó ṣe pàtàkì púpọ̀ kí a gbé èdè Yorùbá lárugẹ. Kìí wá ṣe èdè nìkan, àṣà wa pàápàá, a ò ní fi ọwọ́ rọ́ọ sẹ́yìn ní orílẹ̀ èdè D.R.Y nítorí ara ìdánimọ̀ náà ni àṣà wà.
Bí àpẹẹrẹ, aṣọ wíwọ̀, oúnjẹ wa, ìkíni, iṣẹ́ àdáyébá tí a jogún lọ́wọ́ àwọn babańlá wa àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Gbogbo ìwọ̀nyí ni a óò gbé lárugẹ ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá nítorí pé, àṣà wa kò gbọ́dọ̀ parun, ìdánimọ̀ wa ni.
Gẹ́gẹ́ bí MOA ṣe sọ láìpẹ́ yí wípé, kòsí èdè náà ní àgbáyé tí ó kún tàbí tó dára tó èdè Yorùbá, ṣé irú èdè bẹ́ẹ̀ ni a óò wá fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú, rárá o.
MOA ti jẹ́ kí ó yé wa pé, èdè Yorùbá nìkan ni a óò máa sọ ní ibi gbogbo ní orílẹ̀ èdè D.R.Y. Yálà ní ilé iṣẹ́ tàbí ní ilé ìwé. Èdè Yorùbá ni a óò máa fi kọ́ àwọn ọmọ wa, kí ẹ̀kọ́ náà leè yé wọn dáadáa.
Àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé fún Màmá wa MOA, láti dá wa padà sí orírun wa ni, gẹ́gẹ́ bí MOA ṣe máa ń sọ fún wa. Nítorí náà, gbogbo ohun tí a leè tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bíi ìdánimọ̀ wa ni a óò gbé lárugẹ tí a óò sì máa ṣe wọ́n bí àwọn babańlá wa ti ń ṣeé láti ìpilẹ̀ṣẹ̀.
Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè mi, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).
Bí a ò kú, ìṣe ò tán