A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tó gbé ìránṣẹ́ rẹ̀ ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla dìde fún àwa ìran Yorùbá ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yìí láti gbà wá lọ́wọ́ ìṣẹ́ àti ìyà.
Àwa ọmọ aládé ti jìyà púpọ̀ fún àìmọye ọdún, ṣé ti ebi ni ká sọ ni, àbí ti ọmọ tó kàwé tí kò rí iṣẹ́ tó wá di alárìnkiri láàárín ìlú, ètò ààbò tó mẹ́hẹ ńkọ́?
Bí wọ́n ṣe ń jíwa lọ́mọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń jíwa láya tí wọ́n á sì tún máa béèrè òbítíbitì owó fún ìtúsílẹ̀ wọn.
Ṣùgbọ́n Olódùmarè ti gbà wá, gbogbo rẹ̀ sì ti di àfìsẹ́yìn tí eégún ń fi’ṣọ,nítorí pé màmá wa ti sọ orísìírísìí àwọn ìgbádùn tí yóò wà fún wa ní orílẹ̀ èdè wa tuntun yí nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè ti gbé lé wọn lọ́wọ́, nítorí pé iṣẹ́ yóò pọ̀ yanturu, oúnjẹ yóò wà lọ́pọ̀lọpọ̀, bẹ́ẹ̀ni gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá ni yóò nílé lórí. Gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá Indigenous Yorùbá People IYP, a kú oríire!