Ìròhìn kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láìpẹ́ yí sọ pé, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ gígún ni lọ́bẹ, dída omi ásíìdì sí’ni lára àti fífi ipá bá’ni lò pọ̀ ni ó ṣẹ́lẹ̀ níjọ́ kan ṣoṣo!
Lára àwọn ibi tí aburú wọ̀nyí ti ṣẹlẹ̀ ni Hackeny, Forest Gate, Gorton, Truro, TP Valley (Wales), Peterborough, Torquay Castle Circus, àti Bournemouth. Bẹ́ẹ̀ ni a gbọ́ pé ọ̀rọ̀ tí kò mọ́gbọ́n wá ni àwọn ọlọ́pa kan nsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn ti ìfipá-báni-lòpọ̀.
Gbogbo ojúlówó ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) tó wà ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ẹ ṣọ́ra gidi, kí a máṣe kó sí àgbákò.
Ẹ ránti ọ̀rọ̀ tí Olórí-Ìjọba-Adelé D.R.Y bá wa sọ, láìpẹ́ yí, pé kí a máa pe ara wa lóòrè-kóòrè, kí a máṣe pẹ́ níta lálẹ́, paríparí rẹ̀, kí á máa bọ̀ nílé, ní Orílẹ̀-Èdè Yorùbá!
Orílẹ̀-Èdè wa, D.R.Y, ti kúrò nínú nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún, ó lé méjìlélógún, bẹ́ẹ̀ ni a ti di orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún tí a wà nínú rẹ̀ yí, nígbà tí a ṣe Ìpolongo Ìṣèjọba-Ara-Ẹni D.R.Y, pẹ̀lú ìbúra-wọlé fún Olórí Ìjọba Adelé, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, tí wọ́n sì ti nbáṣẹ́ lọ.
Lóotọ́, àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, ìlú mùjẹ̀mùjẹ̀, ṣì nfi ipá jẹgàba lórí ilẹ̀ wa, ní D.R.Y, ṣùgbọ́n, lágbára Èdùmàrè, wọ́n máa tó sákúrò!