Ìròyìn tí a rí kà lórí ẹ̀rọ ayélujára X fi àwòrán Seyi Tinubu hàn níbi tí ó ti ń bẹ́yín kẹ, tí ó sì ṣàlàyé ohun tí àjọ tí ó dá silẹ dúró lé lórí, ó pe orúkọ àjọ náà ni: Seyi Tinubu matanal and child health intervention, lórí èròngbà láti dín bùkátà à ń ra ogún kù àti ìnira tí àìní ń fi jẹ́ àwọn ènìyàn níyà. Seyi Tinubu a lérò pé ò ka ilẹ̀ Yorùbá mọ́ aríremáṣe Nàìjíríà yín? 

Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá yíká ilé ìwòsàn ọgọ́ta ni inu Orílè-èdè wọn, Nàìjíríà ní ó fẹ́ ràn lọ́wọ́, àti mọ̀ wípé, ó fẹ́ fí owó àwé ṣe àwé ní àlejò ni.

Ẹ ò ri wí pé, ẹni burú mọ̀, ó ń retí ẹni tí ó máa sọ ọ́ fún ní, ìyẹn ni wípé, àwọn náà mọ̀ ibi tí wọ́n bá ayé àwọn ènìyàn jẹ́ dé.

Ẹ wò ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ sí ìgbà’yé gbádùn àwa Indegenous Yorùbá People, (I.Y.P.), tí màmá wa, Olóyè Ìyáàfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá ti fi dá wa lójú pé ìwòsàn ọ̀fẹ́ ni fún gbogbo àwa ọmọ Aládé ní Orílè-èdè Democratic Republic of the Yorùbá, (D.R.Y.).

Tí kìí bá ṣe ti àwọn alágídí àgbèsùnmọ̀mí Nàìjíríà tí wọ́n ń jẹ gàba lórí ilẹ̀ wá ní, gbogbo ayé kò bá ti mọ̀ pé, Orílè-èdè Olómìnira Tiwantiwa tí Yorùbá ti ń dábírà, ṣùgbọ́n, láìpẹ láìjìnà, wọn má bá ìtìjú kúrò tí ìyanu á wá bẹ̀rẹ̀ sí ní máa ṣẹlẹ̀ ní Orílè-èdè wa.

Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá