Nígbà gbogbo ní àwa ìran Yorùbá yóò máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa tó rántí wa sí rere, tó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn amúnisìn nípasẹ̀ màmá onínúure, ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tó rán sí wa.
Àyípadà ọ̀tun ti de bá gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò tí Olódùmarè gbé lé màmá wa MOA lọ́wọ́.
Ètò Ẹ̀yáwó tí kò ní èlé lórí yóò wà fún èyíkéyìí ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá tó bá fẹ́ ṣòwò, níwọ̀n ìgbà tí o bá ti jẹ́ ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá I.Y.P, o ní ẹ̀tọ́ sí ètò ẹ̀yáwó tí a ń sọ yí, tó bá ṣáà ti jẹ́ wí pé fún okòwò ni. Iye tí ẹnìkọ́ọ̀kan bá gbà ni yóò sì san padà láìsí èlé kankan.
Gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ wípé, àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè fún wọn yí, kò sí irú rẹ̀ ní àgbáyé.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí oníkálukú wa máa ronú ohun tí a fẹ ṣe ní kété tí àwọn adelé wa bá ti wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba ní àwọn ìpínlẹ̀ méjèèje tó wà ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.
Ìdúró ò sí, ìbẹ̀rẹ̀ ò sí, gbogbo ìgbà náà ni màmá wa MOA máa ń sọ wípé a ò ní rìn rárá, a máa fò ni, nítorí kò sí nǹkankan nílẹ̀ mọ́. Fún ìdí èyí, ẹ jẹ́ kí a fi ọwọ́sow’ọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adelé wa kí a lè bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn àwọn àlàkalẹ̀ ètò loríṣìíríṣìí tí Olódùmarè ní fún wa.