Ẹnikan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀mọ̀wé Garus Gololo ni a gbọ́ pé ó sọ ọ̀rọ̀ kan, bóyá Haúsá ló ń sọ nínú fọ́nrán náà, a ò kúkú mọ̀! Ṣùgbọ́n, ìkànnì tí a ti rí ọ̀rọ̀ náà lórí ayélujára, sọ pé, Ẹ̀sùn márun ọ̀tọ̀tọ̀ ni Gololo yí kà sí ọrùn ààrẹ wọn Tinúbú ní ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà wọn lọ́hùn-ún.
Ìkíní, ọkùnrin yí sọ pé kànga-epo-rọ̀bì mẹ́tadínlógún ni Tinubú ní, ní agbègbè Niger-Delta, tí òun fún’ra òun mọ̀.
Ìkejì, ó ní àwọn ọmọ Tinubú, Kúnlé àti Wálé, ni wọ́n ń darí ilé-iṣẹ́ ìfọ’po rẹ̀ ní ìlú Malta.
Ìkẹ́ta, ó ní, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ilé-epo OANDO àti ti AGIP, Tinubú ló ni wọ́n.
Ìkẹ́rin, ọkùnrin Gololo yí sọ pé, owó-ìrànwọ́ epo (subsidy) tó sọ pé òun yọ, àpò ara rẹ̀ ló nsan-án sí, ìdí nìyí tí owó epo bẹntiróòlù kò leè wálẹ̀.
ÌKarùn-ún, ó sọ pé ààrẹ wọn ọ̀bún tí gbé àdéhùn-agbaṣẹ́ṣe (kọ́ntiratì) oní tírílíọ́nù márùndínlógún owó náírà fún ara rẹ̀.
Gbogbo rándan-ràndan tí wọ́n nwí yẹn, kò kàn wá o, kí wọ́n ti kó ara wọn kúrò lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y) ni ti wa!
Ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People I.Y.P), a kú oríire, Àwa ti bọ́ nínú ìgbèkùn àṣìtáánì tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nàìjíríà!