Seyi Makinde, àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ pera yín ní àgbà, àgbà òfò, ní ilẹ̀ Yorùbá, pẹ̀lú ẹ̀yin tí ẹ pe ara yín lọ́ba, ní ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n tí ẹ lọ ńrán àwọn èèyàn sí awon ọmọ Yorùbá tí ẹ jí gbé, pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun Orílẹ̀-Èdè wa, Democratic Republic of the Yoruba, tí ẹ jígbé, ní àkókò tí wọ́n dúró lórí ẹ̀tọ́ wọn, gẹ́gẹ́bí ọmọ Yorùbá àti ọmọ-ogun Orílẹ̀-Èdè D.R.Y, lórí Ilẹ̀ babańlá wọn, ilẹ̀ D.R.Y, tí ẹ ní pe kí wọn máa yí wọn lọkàn padà; pàápàá àwọn àgùnbánirọ̀ tí ẹ rán, láti máa jẹ́ kí àwọn kan lára àwọn ọmọ Yorùbá àti ọmọ-ogun wa ó máa wípé ṣeni wọ́n ti àwọn jáde láti wá dúró fún òmìnira Ìran Yorùbá, àti láti máa wípé àwọn kò mọ nkankan rárá; a fẹ́ fi àkókò yí sọ fún yín pé, gbogbo ìgbésẹ̀ yín pátápátá ni a mọ̀.
Gbogbo bí ẹ ṣe ń fi ìyà jẹ àwọn ọmọ wa àti ọmọ-ogun wa ti wọ́n kọ̀ jálẹ̀, nínú wọn, wípé, títí láí, ti ìran Yorùbá ni àwọn ńṣe; gbogbo rẹ̀ pátá ni a rí, tí a sì ti ń bá yín kó wọn jọ sínú ìwé-àkọsílẹ̀ ti Orílẹ̀-Èdè Yorùbá.
Ní àkọ́kọ́, a fẹ́ jẹ́ kí ẹ mọ̀ wípé, Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti dúró gẹ́gẹ́bí orílẹ̀-èdè ti ara rẹ̀ o, tí kò sì sí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun tí ó leè yí èyí padà.
Èkejì, ni wípé, àwọn ọmọ-ogun Orílẹ̀-Èdè Yorùbá (D.R.Y) àti àwọn Ọmọ Yorùbá tó kù, tí ẹ jígbé wọ̀nyí, wọn kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ kankan rárá lábẹ́ òfin kankan ní àgbáyé.
Ẹ̀tọ́ wọn ní wọ́n dúró lé lórí gẹ́gẹ́bí ọmọ Yorùbá, àti ọmọ-ológun Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ní ilẹ̀ Orílẹ̀-Èdè wọn, Orílẹ̀-Èdè Yorùbá.
Ìdí nìyí tí a kò fi nílò agbẹjọ́rò kankan lórí ọrọ̀ yí, nítorí pé, orí ilẹ̀ wa ni a wà, gẹ́gẹ́bí Orílẹ̀-Èdè aṣèjọba-ara-ẹni, tí ó yàtọ̀ sí Nàìjíríà.
A ti jáde kúrò nínú Nàìjíríà yín láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, tí a sì ti ṣe ìbúra-wọlé fún Olórí Ìjọba-Adelé wá, Bàbá wa, Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ, láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún; Ṣáájú ìgbà náà ni a sì ti kọ̀wé ránsẹ́ sí ìwọ Ṣèyí Mákindé wípé a ń bọ̀ láti wá gba nǹkan tí ó jẹ́ ti Orílẹ̀-Èdè Yorùbá, tí ẹ sì bu ọwọ́ lu ìwé náà pé ẹ ti ri gbà. Nítorí náà, kí ẹ yáa mọ̀, pé, Orílẹ̀-Èdè niwá, tí a sì ti dá dúró lábẹ́ Òfin ní Àgbáyé.
Orílẹ̀-Èdè wa la wa, tí ìwọ Ṣèyí Mákindé ti wá kọlu àwọn ọmọ-ogun wa, pẹ̀lú àwọn ọmọ Yorùbá wa míràn, tí ẹ kó lọ. Nítorí èyí, ìwọ ni o tọ́ ìjà, ìwọ ni o ṣe àkọlù sí ọmọ-ogun D.R.Y, àti sí àwọn ọmọ Yorùbá míràn, lórí ìlẹ̀ Orílẹ̀-Èdè D.R.Y. Ìwọ lo jẹ̀bi.
Seyi Makinde, o túbọ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ lójoojúmọ́ ni. Láìpẹ́, láìjìnnà, ìdájọ́ rẹ yíò dé, tí kò sì ní sí ibi tí o máa sá wọ̀.
Ṣé ẹ wá rí ẹ̀yin tí ẹ pe ara yín ní àgbà, àgbà ìsọnu, ní ilẹ̀ Yorùbá, àti ẹ̀yin tí ẹ ńpe ara yín lọ́ba, tí ẹ torí àtẹnujẹ, tí ẹ ńta Ìran yín, àwọn ònilẹ̀ Yorùbá ti bínú sí gbogbo yín, pátápátá, àti ẹ̀yin àti àwọn ìdílé yín.
Bákan náà, ẹ̀yin àgùnbánirọ̀, tí wọ́n ńrán nísẹ́ wípé, nítorí pé ẹ jẹ́ ọ̀dọ́, kí ẹ lọ máa bá àwọn ọmọ Yorùbá, àti àwọn ọmọ-ogun D.R.Y tí Ṣèyí Mákindé jí gbé, sọ̀rọ̀, láti yí wọn lọ́kàn padà; ǹjẹ́ ẹ tilẹ̀ ní ìrètí ọjọ́ ọ̀la tí ó dára bí? Àwọn tó ti ṣe àgùnbánirọ̀ bíi tiyín láti ǹkan bí ogún ọdún, ọgbọ̀n ọdún, sẹ́yìn, mélo nínú wọn ló rí iṣẹ́ fi ìwé-ẹ̀rí wọn ṣe?
Àwọn tí wọ́n ńrán yín nísẹ́ ibi yí, wọn ò ní ètò kankan fún yín ju wípé, lẹ́yìn tí ẹ bá ti parí ilé-ẹ̀kọ́ tán, kí àwọn tó jẹ́ ọkùnrin nínú yín lọ máa gun ọ̀kada, tàbí ṣe yahoo, kí àwọn obìnrin yín sì máa ṣe òwò ìṣekúṣe kiri.
Ní ti ẹ̀yin agbẹjọ́rò, tí a bá rí èyíkéyi nínú yín tí ó bá gbé ẹnu rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ yí, àgàgà tí ó bá tún lọ jẹ́ ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, kí ó mọ̀ wípé òun ti sọ ìjẹ́-ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá òun nù nìyẹn; kò sí ní ní ẹ̀tọ́ kankan, bó ti wù kí ó mọ, láyé, ní ilẹ̀ Yorùbá.
A ńfi àkókò yí kan sárá sí àwọn ọmọ-ogun wa, àti gbogbo àwọn ọmọ Yorùbá tí wọ́n dúró, tí wọn kò yẹ’sẹ̀, àti àwọn ẹbí wọn. Ìran Yorùbá mọ rírì yín o. Díẹ̀ kékeré báyìí náà ló kù; ẹ túbọ̀ tẹ̀ síwájú, Ìran Yorùbá kò ní gbàgbé yín láíláí.