Ó ti dójú ẹ̀ báyìí. Ó sì gba omijé lójú ẹni tó bá mọ iyì ọmọ. Yorùbá bọ, wón ní, ọmọ ni iyì, ọmọ lèrè, ọmọ laṣọ, ọmọ lalẹ́.

Ṣùgbọ́n nínú fọ́nrán kan tí a rí lórí ayélujára, ọmọ ọwọ́ oṣù márùn-ún ti wá di ohun tí a nfi ṣe pàṣípààrọ̀ fún ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ti ìgbàlódé (Android).

Nínú fọ́nrán yi l’a ti rí abiyamọ kan tó sọ̀rọ̀ pé òun fẹ́ fí ọmọ òun, ọmọ oṣù márùn-ún, ṣe pàṣípààrọ̀ fún fóònù, aṣọ, bàtà, àti owó . Ìṣẹ̀lẹ̀ yí ṣẹlẹ̀ ní ìlú Abẹ́òkúta, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá níbi tí ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà ń fipá je gàba lé lórí. 

Wọ́n bií lérè pé kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà. Ó dáhùn pé òun kò ní bojú w’ẹ̀yìn mọ́ láti wá gba ọmọ náà láéláé. Àwọn tó nba sọ̀rọ̀ sì sọ pé kòburú.

Kíni ká ti wá sọ sí irú èyí? Ẹ̀yin abiyamọ òtítọ́, l’ọkùnrin, l’obìnrin, ọ̀rọ̀ kàyéfì rèé.

Nítorí pé èyí ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y) ló fi jẹ wá l’ogún. Ọ̀rọ̀ tó ba’ni nínú jẹ́ gbáà ni.

Ara àbájáde ìjẹgàba àwọn gómìnà agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí wọ́n jẹgàba lórí ilẹ̀ wa, D.R.Y, nìyìí.

Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, irú iwa apanilẹ́kún yí kò lè wáyé. Abiyamọ náà ti rò ó pin dé bi pé ọ̀rọ̀ náà yọrí sí àrùn ọpọlọ fún, ló wá gbé ọmọ oṣù márùn-ún lọ ṣe pàṣípàrọ̀ fún fóònù, aṣọ àti bàtà. Ólékenkà!

Ẹ̀yin aríremáṣe agbésùnmọ̀mí gómìnà-Nàìjíríà mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ tí ó jẹgàba lórí ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ọ̀dájú ni yín.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates 28/09/2024

Ẹ fi  agídí tó máa kó bá yín dúró lórí ilẹ̀ D. R. Y. Dídúró yín sí’bi tí kì nṣe ti’yín npa àwọn ará ìlú lẹ́kún ni, ìyà ló jẹ́ fún àwọn ọmọ aládé, ọmọ ológo tí Ọlọ́run mọ̀ọ́mọ̀ bùkún lọ́pọ̀lọpọ̀ pèlú àwọn àlùmọ́nì lóríṣiríṣi.  

Gbogbo ọmọ Yorùbá, njẹ́ ẹ mọ̀ pé, ara nkan tí Màmá wa, Oloye Ìyá-Ààfin Modupeọla Onitiri-Abiọla tẹnu mọ́ rèé. Tí wọ́n ké tantan, tí wọ́n sì pàrọwà fún wa pé kí a tètè ṣe ohun tí a nííṣe, nígbà náà l’ọhún.

Ṣé kò ba’ni nínú jẹ́ pé a nfi ojú rí nkan báyìí.

A wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó gbé Màmá wa, Oloye Ìyá-Ààfin Modupeọla Onitiri-Abiọla, dìde ní àsìkò yìí àti dédé ìwòyí.

Tí wọ́n jà fita-fita fún òmìnira àwa ọmọ aládé, ọmọ ológo, Indigenous Yoruba People (I.Y.P) ti D.R.Y. 

Èyí ló fún wa ní ìrètí ọjọ́ ọ̀la tó dára. Àsìkò imura fún ayọ̀ abara-tíntín àti ijó gbogbo àwa ọmọ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) tí dé, láṣẹ Èdùmàrè. A dúpẹ lọ́wọ́ Màmá wa, MOA, tí wọ́n ò fi wá ṣe pàṣípààrọ̀.

Wàyí o!  A fi ohùn ìkìlọ̀ ránṣẹ́ sí gbogbo ẹ̀yín gómìnà agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà tí ẹ njẹgàbà lórí ilẹ̀ D.R.Y: Sanwó-Olú Jide, Dapo Abiodun, Oyebanji, Adeleke, Ayedatiwa, Abdulrazak, Ṣèyí Mákindé ati Ododo, pé kí ẹ kúrò ní ilé-iṣẹ́ Ìjọba D.R.Y. Àwa ọmọ ìbìlẹ̀ ti dé.