Òyìnbó kan ni o!

Pẹ̀lú ìgboyà tó ní agbára gidi, ló fi tú gbogbo àwọn àṣírí òyìnbó ẹgbẹ́ rẹ̀.

Ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, ó ní, ohun gbogbo ni ó lè yípadà ní ayé yí, ní àárín ogún ọdún pàápàá, ṣùgbọ́n ohun kan ni àwọn òyìnbó kò gbà kí ó yípadà o!

Kíni ohun náà?

Ìjẹgàba Òyìnbó, ìjẹgàba tì’pá-ti’kúùkù, tí wọ́n ń jẹgàba lórí ọrọ̀-ajé orílẹ̀ èdè aláwọ̀dúdú, fún ìlú tiwọn, wọn ò gbà kí ohunkóhun láyé kí ó yí èyí padà o!

Ọkùnrin náà ṣe àlàyé,wípé, láìsí ilẹ̀ aláwọ̀dúdú, àlùmọ́ọ́nì aláwọ̀dúdú, pẹ̀lú ènìyàn aláwọ̀dúdú pàápàá, èyí tí wọ́n ń kó lẹ́rú, tí wọ́n sì ń jí, kòní sí àwọn tó njẹ́ aláwọ̀-funfun o!

Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tan aláwọ̀dúdú pé aláwọ̀-funfun ní ọgbọ́n jù wọ́n lọ!

Ọkùnrin yí wá ṣe àlàyé pé, ohun gbogbo ni àwọn aláwọ̀-funfun ti gbà láàyè láti yípàdà, láarín ọgọ́run ọdún s’ẹyìn, ṣùgbọ́n ìjẹgàba aláwọ̀-funfun lórí ọrọ̀-ajé orílẹ̀ èdè aláwọ̀dúdú, ni wọn ò tíì yípadà kúrò ní bí ó ti wà láti àìmọye ọdún, wọn kò jẹ́ kí ìyẹn ó yí padà o!

Ọkùnrin náà sọ pé, àìmọ̀kan,àwọn aláwọ̀ dúdú, ni wọ́n fi máa nrò pé ọ̀gá ni òyìnbó; ó ní rárá o! Àlùmọ́ọ́nì tí wọ́n bá tí jí ní ọ̀dọ̀ àwa aláwọ̀dúdú, òun ni wọ́n fi ń ṣe àwọn ohun mère-mère tí wọ́n fi dà bí ẹni pé àwọn ni Igbákejì-Olódùmarè, tí aláwọ̀dúdú á wá máa bọ wọ́n!

Ọkùnrin náà wá fi yé gbogbo olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà pé, kí wọ́n mọ̀ pé ọjọ́ tí Áfríkà bá ti kọ̀, tí wọn ò gbà kí aláwọ̀-funfun máa kó àlùmọ́ọ́nì wọn lọ sí òkè-òkun mọ́, ọjọ́ yẹn ni aláwọ̀funfun di ẹni-yẹpẹrẹ ní àgbáyé.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates 03/09/2024

Èyí ga jù; a ti wá rí òtítọ́ tí màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá, ti máa ń sọ fún wa pé, èkíní, aò ní ti oko-ẹrú kan bọ́ sí èkejì, ìbáà ṣe oko-ẹrú lábẹ́ òyìnbó tàbi lábẹ́ àwọn ọmọ-àlè, tí wọ́n pera wọn ní Yorùbá, tí ó jẹ́ olóṣèlú ajẹgàba Nàìjíríà.

Èkéjì, Màmá sọ fún wa pé, a ò ní gbé àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì wa lọ sí ìlú-òkèèrè ní rọ̀bì ṣùgbọ́n, pẹ̀lú àṣẹ Olódùmarè, aó máa yi sí ohun tó lówó lórí gidi, kí á tó tàá sí ìta.

Wọ́n tún tẹ̀ síwájú pé, ohun tí a bá nílò, a máa fún’ra wa ṣe; ohun tí a bá sì ṣe yẹn, òun náà ni a ó lò.

Àwa ti bọ́ pátápátá nínú oko-ẹrú òyìnbó ní kété tí a ti bẹ̀rẹ̀ ìṣe-ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y)