Arákùnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Yọmi Ọlalẹyẹ ni ọwọ́ àwọn agbófinró ti tẹ̀ o, tí wọ́n sì ti fi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀, jẹgúdújẹrá àti jíjalè ìdánimọ̀ kàn látàrí ipa tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn- án pé ó kó nínú ètò ìrànwọ́ fún àwọn ènìyàn tí kò ní iṣẹ́ ti oní mílíọ̀nù mẹ́wàá dọ́là tí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà gbé kalẹ̀.
Ṣèbí ara àwọn àtúbọ̀tán ìwà ibi tí àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní olóṣèlú àti àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá ń hù náà ni eléyìí.
Nígbà tí wọ́n ti jẹ ayé àwọn ọ̀dọ́ mọ́ ayé ti wọn tán, tí kò sì ku ohunkóhun sílẹ̀ fún àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn, èyí ló mú kí oníkálukú máa fi ìlú sílẹ̀ láti lọ máa wá ibi tí ayé yóò ti dẹrùn fún – un.
Àwa ìran Yorùbá tó jẹ́ wí pé, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni ó jáde láti lọ máa ṣe ẹrú níbì kankan pẹ̀lú gbogbo àlùmọ́ọ́nì tí Olódùmarè fi fún wa, gẹ́gẹ́ bí màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè lò fún wa láti gbà wá ní àkókò yí se máa ń sọ fún wa wípé, ṣúgà ni àwa ìran Yorùbá jẹ́, àwọn orílẹ̀ èdè míràn ni yóò máa wá bá wa.
Nítorí náà, a ń fi àkókò yí sọ fún àwa ọmọ orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá wípé, ẹ má jẹ́kí a sọ ìwà ọmọlúwàbí wa nù ní gbogbo ibi tí a bá wà, ògo adúláwọ̀ ni àwa ìran Yorùbá jẹ́, ẹ jẹ́ kí a ní sùúrù, àkókò díẹ̀ lókù fún wa.
Ẹ sì jẹ́ kí a ríi dájú wípé, a jẹ́ olóòótọ́ àti olódodo nínú ohun gbogbo tí a bá ń ṣe, nítorí pé orílẹ̀ èdè Democratic Republic of the Yorùbá (DRY) kò ní gba ìgbàkugbà rárá, ẹnikẹ́ni tí ó bá f’ọwọ́ pa idà òfin lójú, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni yóò gba ìdájọ́ rẹ̀ láìsí ojúsàájú.