Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nkan ni àwọn òyìnbó amúnisìn ti yí mọ́ wa lọ́wọ́: gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ṣe sọ, wọ́n ní àwọn amúnisìn wọ̀nyí kò jẹ́ kí á mọ ẹni tí a jẹ́ ní àgbáyé yí: bí a ṣe jẹ́ aṣáájú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Wọ́n tún sọ, wọ́n ní àwọn nkan tó jẹ́ àṣà wa, àwọn òyìnbó wọ̀nyí tún fẹ́ sọ-ọ́ di nkan tí kò dára! Háà! Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n ti yí wa ní ọpọlọ sí ibi tí kò dára: ohun tí Ọlọ́run fi jínkí wa pàápàá, wọ́n njẹ́ kí a máa wòó gẹ́gẹ́bí ohun tí kò dára.
Èyí ló ṣe okùnfà ìròyìn yí; nítorí ohun kan tí a rí kà lórí ẹ̀rọ ayélujára X fi hàn gbangba pé ohun tí a npè ní owó-ẹyọ (cowrie) ṣe iyebíye, ó sì ní àwọn kókó ìtumọ̀ àti lílò pàápàá.
Ní ilẹ̀ Yorùbá, kí wọ́n tó sọ ohun gbogbo di àdàmọ̀dì, njẹ́ a mọ̀ pé a máa nfi owó-ẹyọ san owó-orí ìyàwó!? Kò sí bí o ṣe le ní owó tó, bàbá ìyàwó kò le fún ẹ ní ọmọ ẹ̀ láti fẹ́ tí o ò bá mú iye tí wọ́n ni kó-o mú wá ní owó-ẹyọ gẹ́gẹ́bí owó-orí ìyàwó! Èyí kìí ṣe ayé-àtijọ́ ran-ran-ran o! Inkan bí ogójì ọdún sẹ́yìn péré ni a nsọ yí o!
Yàtọ̀ sí èyí, owó-ẹyọ jẹ́ owó tí ó jẹ́ owó gidi tí a nná láti ṣe káràkátà gẹ́gẹ́bí a ṣe nná oríṣiríṣi owó lóni! Ó jẹ́ owó tí àwọn ènìyàn ti ná dáadáa kí wọn tó máa pe nkan míì ní owó fún wa!
Bẹ́ẹ̀ ni owó-ẹyọ ní ìtumọ̀ nínú ẹ̀mí – owó-ẹyọ jẹ́ ohun tí àwọn oríṣiríṣi ènìyàn ní ìmọ̀ pé ó nííṣe pẹ̀lú ọrọ̀-níní, àti pé ó nííṣe pàápàá pẹ̀lú ààbò nínú ẹ̀mí, àti fún ìtọnà sí kàdárà ẹni layé.
Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ẹ jẹ́ kí á ni lọ́kàn pé, pípadà tí a padà sí orísun wa yí, a padà sí ilé-ẹ̀kọ́ ni o! Olódùmarè (ẹni tí òun fún’rarẹ̀ jẹ́ Odù-Àìnípẹ̀kun) ní Olùkọ́ni wa o! Pẹ̀lú àánú, yíò mú wa padà sí orísun wa nítòótọ́; a ó sì yí ọpọlọ wa padà kúrò ní ọ̀nà tí àwọn amúnisìn ti darí wa sí tẹ́lẹ̀! A ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìfẹ́ Olódùmarè, kìí ṣe àwọn ìfẹ́ òyìnbó-amúnisìn!