Obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Candace Owens, sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára nígbàtí ó ń ṣàlàyé nípa ọ̀rọ òwò ẹrú ní Áfríkà. Ó ní àwọn ènìyàn sọ pé ìkónilẹ́rú ní Áfríkà bẹ̀rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn aláwọ̀ funfun Yúróòpù. Ó wípé kò rí bẹ́ẹ̀ ràrá o.

Gẹ́gẹ́bí ó ṣe sọ; ó ní ó pọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó kù ní àgbáyé náà. Ó ní Áfríkà pàápàá kún fún ìwà imunisin àti ìkónilẹ́rú, ó tó mílíọ̀nù ọmọ Afrika tó wà ní ìgbèkùn oko ẹrú ni Áfríkà báyi, tí àwọn ọmọ Afríkà bíi tiwọn kò l’ẹ́rú.

Ó wá béèrè pé, kí ni ìdí ti àwọn tó pe ara wọn ní aṣíwájú láàrín àwọn tí wọ́n ní àwọn njà láti fòpin sí ìnilára aláwọ̀ dúdú kò sọ̀rọ̀ nípa èyí rárá? Ìdáhùn rẹ̀ ní pé wọn kìí ṣe aṣíwájú rárá, ṣùgbọ́n alọ́nilọ́wọ́gbà ní wọ́n jẹ́.

Kíi se pé obìnrin yí  jẹ́ abẹnugan fún àwọn òyìnbó nìkan,ìgbìyànjú rẹ̀ ni làti máṣe jẹ́ kí á fojú sí ìwà ìkà wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni a ò lè sọ pé irọ́ ni gbogbo ohun tí ó sọ, ṣùgbọ́n àwọn aláwọ̀ funfun yí náà ni ọ̀gá amùnisìn tó ń nkọ́ àwọn aṣíwájú àti olóṣèlú Áfríkà ní ìwà ìmúnilẹ́rú t’òde òní, àti pé olórí-ẹrú àwọn òyìnbó ni wọ́n jẹ́, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ láti kó àwọn ènìyàn wọn lẹ́rú fún ìgbádùn àwọn aláwọ̀ funfun.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Ó yẹ kí a dúpé lọ́wọ́ ìyá wa ìrọ̀rùn ló bá dé, ìyá ààfin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla, tí Olódùmarè lò láti gbà wá kúrò nínú ìlú agbèsùnmọ̀mí Naijiria, ní ogúnjọ́, oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lélógún, tí àwa sì ti dúró bí Orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni, láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún. 

Nínú àlàkalẹ ètò ìṣèjobà tí Olódùmarè ti gbé fún Ìran Yorùbá nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, màmá wa, kò sí àyè fún irú ìwà pálapàla báyìí ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y). Màmá wa ti sọ fún wa pé àparò kan kò ní ga jù kan lọ. Ẹnìkan kò ní mú enikan lẹ́rú rárá.

Ní àkótán, ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People IYP) kankan kò ní ṣe ẹrú ẹnikẹ́ni, nítorí ọmọ-Aládé ni gbogbo wa.

Àkókò náà ti dé báyìí o, fún gbogbo àwa Indigenous Yorùbá People, I.Y.P, láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjọba-Adelé wa. Ọ̀rọ̀ yí wá kan Gbogbo àwa ọ̀dọ́ I.Y.P, nítorí pé ọ̀dọ́ ni yóò ṣe ìjọba ní orílẹ̀ èdè D.R.Y.