Ní àìpẹ́ yí ni Ìyá Wa, Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí Ìran Yorùbá, Màmá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá bá gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y), sọ̀rọ̀; wọ́n bá wa sọ gbólóhùn díẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ owó àwọn aríremáṣe Nàìjíríà, àti bí àwa D.R.Y kò ṣe ní ohunkóhun láti ṣe papọ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà.
Nàìjíríà kò ṣe ìdánimọ̀ wa, àwa náa, a ò ṣe ìdánimọ̀ Nàìjíríà.
Látàrí pé agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà kò ṣe ìdánimọ̀ wa, nípa jíjẹgàba sórí ilẹ̀ wa, tí àwa náà, a ò sì ṣe ìdánimọ̀ rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jé pé kìí ṣe orílẹ̀-èdè, ètò amúnisìn ni ; latàrí pé àwa náà kò ṣe ìdánimọ̀ Nàìjíríà tí ó nṣe ìkà fún ọmọ Yorùbá, nítorí èyí, Màmá sọ pé D.R.Y kò ní gba owó náírà kankan tí ó wà báyi nínú àwọn ilé-ìfowópamọ́, D.R.Y kò ní yí owó náírà wọ̀nyẹn sí owó D.R.Y. Ṣùgbọ́n, Màmá sọ pé èyí kò túmọ̀ sí pé kí ọmọ-ìbílẹ̀-Yorùbá (I.Y.P) ó wá máa ní ìjayà lórí owó wọn.
Màmá sọ pé owó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) tí ó jẹ́ náírà, ṣebí inú àpò ilé ìfowópamọ́ tí ẹ fi sí ni ó wà? D.R.Y kò ní yi sí owó wa, àmọ́ àárín ẹ̀yin àti ilé-ìfowópamọ́ náà ni ó wà! Tí ilé ìfowópamọ́ náa bá ṣì fẹ́ máa ṣòwò ní orí ilẹ̀ D.R.Y, ó di dandan kí wọ́n tẹ̀lé òfin D.R.Y.
Tí wọ́n bá ti tẹ̀lé òfin D.R.Y, kò s’éwu; ṣùgbọ́n D.R.Y kò ní gba owó náírà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ohun tí òfin D.R.Y bá sọ ni wọ́n máa tẹ̀lé, ilé-ìfowópamọ́ náà á sì sọ fún yín bí ọ̀rọ̀ owó yín tí ó wà lọ́wọ́ wọn ṣe jẹ́; ṣùgbọ́n pé kí a máa bẹ̀rù yẹn, kò sí ìdí fún ìbẹ̀rù bíó tilẹ̀ jẹ́ pé D.R.Y kò ní gbà owó náírà tí ó wà nínú àpò ìfowópamọ́ yín, ṣùgbọ́n ilé-ìfowópamọ́ tí ẹ bá d’òwò pọ̀ tí ilé-ìfowópamọ́ náà sì gbà láti ṣíṣẹ́ ní ilẹ̀ Yorùbá, kí wọ́n sì máa tẹ̀lé òfin D.R.Y, ilé-ìfowópamọ́ náà ni ó mọ bí owó yín kò ṣe ní ní wàhálà kankan.
Ṣùgbọ́n ilé-ìfowópamọ́ tí kò bá lè tẹ̀lé òfin D.R.Y, tí wọn ò sì lè dúró, nípa bẹ́ẹ̀, ní orí-ilẹ̀ D.R.Y, ìyẹn náà kò b’ewu dé, torí ọ̀rọ̀ ilé-ìfowópamọ́ káàkiri àgbáyé, ó ní bí wọ́n ṣe nṣe ètò rẹ̀. Ilé-ìfowópamọ́ tí kò bá le dúró lórí ilẹ̀ D.R.Y, wọ́n á sọ fún àwọn oníbarà wọn ibi tí wọ́n bá nkó ilé-iṣẹ́ wọn lọ, àti bí àwọn oníbarà wọn ṣe máa rí owó wọn gbà.
Kókó ọ̀rọ̀ ni pé D.R.Y kò ní gba náírà tó wà nínú àpò ìfowópamọ́ ẹnikẹ́ni. Ẹni tó bá fẹ́ owó ilẹ̀ Yorúbá, wọ́n lè yí owó náírà tí ó wà nínú àpò ìfowópamọ́ wọn sí owó tí D.R.Y bá ṣe ìdánimọ̀ rẹ̀, lẹ́yìn ìyẹn kí wọ́n wá fi ìyẹn gba owó D.R.Y.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kò sí ìbẹ̀rú fún I.Y.P, owó ẹnikọ̀ọ̀kan tó wà ní ilé-ìfowópamọ́, ilé-ìfowópamọ́ yẹn ló máa sọ fún wọn bí ọ̀rọ̀ owó náírà ọ̀hún ṣe máa jẹ́, ṣùgbọ́n D.R.Y kò ní gba owó náírà tí ó wà ní àpò ilé ìfowópamọ́ kankan.