Ààrẹ orílẹ̀ èdè Burkina Faso, ọ̀gágun Ibrahim Traore sọ wípé ìjọba òun yóò kọ́ ilé ìwé gbogbonìṣe àti ilé ìwé gíga Fásítì fún àwọn ọ̀dọ́ ọlọ́pọlọ pípé ti orílẹ̀ èdè náà láti lè dènà bí àwọn ọ̀dọ́ ìlú wọn ṣe lọ ń kàwé lókè òkun ṣùgbọ́n tí wọ́n kò sì ní padà wá sí’lé mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ka ìwé náà tán.
Ó wípé kíkọ́ àwọn ilé ìwé yí yóò fún àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀ èdè náà ni àǹfààní láti sin ilẹ̀ bàbá wọn, tí wọn ò ní gbé ẹ̀bùn ọpọlọ pípé tí Olódùmarè fún wọn lọ sí orílẹ̀ èdè mìíràn láti lọ lòó níbẹ̀.
Ohun tí màmá wa Olóyè ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla máa ń sọ nìyí pé, ògo pọ̀ lára àwọn ọ̀dọ́ wa gidi, ìdí nìyí tí màmá wa MOA sì fi máa ń sọ pé ọ̀dọ́ ní yóò ṣe ìjọba ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).
Nípa tí ètò ẹ̀kọ́, gẹ́gẹ bí àlàyé tí màmá wa alálùbáríkà ṣe fún wa lórí àlàkalẹ̀ ètò ìṣèjọba tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́, ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ yóò wà fún gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba D.R.Y), láti ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ilé ẹ̀kọ́ àkọ́gboyè àkọ́kọ́ ní Fásitì. Iṣẹ́ tó dára ti wà fún wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá parí ẹ̀kọ́ tán, pẹ̀lú àwọn ohun am’áyédẹrùn, àti pé, ọ̀sẹ̀ méjì-méjì ni àwọn òṣìṣẹ́ yóò máa gba owó ọ̀yà wọn.
Nípa bẹ́ẹ̀, kòsí ọ̀dọ́ tí yóò fẹ́ lọ ṣe ẹrú nílẹ̀ àjòjì, tí kò tún sí iṣẹ́ tó dára àfi iṣẹ́ ìdọ̀tí tí àwọn ọmọ tiwọn kò leè ṣe. Nítorí náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́ wa, ẹ jẹ́ kí a f’ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adelé wa, kí a sì ríi dájú pé a sa ipá wa láti lo ẹ̀bùn tí Olódùmarè fún wa fún ìtẹ̀síwájú ati ìgbéga Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.